Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Èkó fọwọ́ sí òfin ìṣúná owó ọdún 2023

0 271

Gomina Babajide Sanwo-Olu ti Ipinlẹ Eko ti fọwọ si ofin iṣuna owo ọdun 2023 fun Ipinlẹ yii lati di amulo, eleyii ti Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko sọ di ofin ninu oṣu kejila ọdun 2022.

O woye pe, iṣuna ọlọdọọdun naa yoo wulo pupọ lati pari awọn iṣẹ akanṣe ilu to n lọ lọwọ. O ni:

“Yoo tun wulo lati fi mu igberu ba awọn iṣẹ iranlọwọ fun awọn ara ilu. A tun jẹ ki ijọba le ṣe aṣeyọri ninu erongba iṣelu ti wọn pe ni ‘T.H.E.M.E’ ati pe iṣuna owo naa yoo mu alekun ba eto iṣuwona ilu ati awujọ lapapọ”  

Eto iṣuna owo ilu ọdun 2023 onitiriliọnu kan le miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹrin le diẹ naira (N1.768 T) ni iko mejidinlọgọta ninu ida ọgọrun jẹ inawo iṣẹ akanṣe, nigba ti iko mejilelogoji ninu ida ọgọrun jẹ inawo onigbadegba, bi owo awọn oṣiṣẹ, awọn inawo ẹnu iṣẹ ati owo ti wọn yoo fi san gbese ilu.

Gomina ṣalaye pe, iṣẹ akanṣe ọkọ oju-irin igbalode onikilomita mẹtadinlogoji (37) laarin agbegbe Agbado si Ebute-Mẹta ati oju ọna igbalode laarin agbegbe Mile 2 si Okokomaiko ti wa ninu iṣuna-owo yii.

Gomina Sanwo-Olu fi kun ọrọ rẹ pe iṣẹ akanṣe ile-iwosan gbogboogbo agbegbe Ọjọ ati ile-iwosan pataki fun itọju eyin ni agbegbe Ketu-Ereyun to n lọ lọwọ yoo pari laipẹ. O ni:

“Awọn iṣẹ akanṣe kikọ ile-ẹkọ, ati oju ọna to n lọ lọwọ ni ilu Badagry, Amuwo-Ọdọfin, Ikorodu, ati Eti Ọsa yoo di pipari laipẹ.”

“Inu mi dun lati fọwọ si ofin iṣuna-owo ọdun 2023, eleyii ti wọn fi ṣowọ si mi lẹyin ti Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti fọwọ si i. Iṣun-aowo ilu yii ti gba ọpọlọpọ ayẹwo kọja ki a to le fọwọ si i bayii. Eto iṣuna owo yii yoo moju to ọpọ nnkan ti awọn ara Ipinlẹ Eko nilo.”

Gomina fọwọ si ofin iṣuna-owo ọdun 2023 yii lati di amulo nibi ayẹyẹ ranpẹ ti wọn ṣe ninu ofiisi rẹ ni Alausa Ikeja pẹlu awọn igbimọ alaṣẹ rẹ ati ọmọ ẹgbẹ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, bi, Igbakeji Gomina, Ọmọwe Ọbafemi Hamzat, Alakoso agba fun eto Idajọ/Agbẹjọro agba fun Ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Moyọsọrẹ Onigbanjo, Alaga Igbimọ fun Iṣuna-owo ilu ninu Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Gbọlahan Yishau, ati Alakoso agba fun Ọrọ-Aje, ati eto Isuna owo ilu ni Ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Sam Egube.

Ẹwẹ, Gomna Sanwo-Olu wa fi ẹmi imoore han si awọn alaṣẹ Ile Igbimọ Aṣofin labẹ oludari Ile, labẹ oludari Ile, Aṣofin Mudashiru Ọbasa fun iṣẹ takuntakun wọn lori abadofin naa ati bi wọn ṣe tete gba a wọle.

O tun ṣe ileri pe ijọba yoo ṣamulo eto iṣuna owo naa ni pipe, ati pe awọn ko ni jẹ ki ọrọ eto idibo to n lọ lọwọ ṣe idiwọ fun awọn iṣẹ ijọba.

Alakoso agba fun Ọro-Aje ati eto iṣuna owo ilu, Ọgbẹni Sam Egube sọ pe, awọn atupalẹ inu eto iṣuna-owo naa fi ifẹ awọn ara ilu kaakiri Ipinlẹ Eko han, ti yoo si mu erongba idagbasoke ipinlẹ yii wa si imuṣẹ.

Ẹwẹ, Alaga Igbimọ fun Iṣuna-owo ilu ninu Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Gbọlahan Yishau, dupẹ lọwọ Gomina fun fifi iwe iṣuna-owo naa ṣọwọ si Ile Aṣofin naa, paapaa to mu u rọrun lati ṣiṣẹ le lori. Ati pe Ile Aṣofin naa ti ṣiṣẹ kikun lori abadofin iṣuna-owo naa ki o to jade gẹgẹ bi ofin bayii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button