Ilé Aṣòfin Èkó fọwọ́ sí àwọn orúkọ mẹ́ta tí ̣Gómìnà fi ṣọwọ́ sí wọn fún ipò aláṣẹ
Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko labẹ Oludari Ile Aṣofin naa Aṣofin Mudashiru Ọbasa, ti fọwọ si awọn orukọ ti ̣Gomina Babajide Sanwo-Olu fi ṣọwọ si Ile wọn gẹgẹ bi ara igbimọ alaṣẹ ẹka amuṣẹṣe ijọba Ipinlẹ Eko
Ile Aṣofin naa fọwọ si yiyan Ọgbẹni Abiọdun Ogunlẹyẹ fun ipo Alakoso-agba, ati awọn meji miiran fun ipo Olugbaninimọran agba si Gomina.
Ṣaaju fifọwọ si awọn eniyan naa, Aṣofin Mojeed Fatai, Alaga fun Igbimọ Tẹẹkoto to ṣagbeyẹwo awọn orukọ naa sọ fun Ile Aṣofin yii pe, awọn ṣiṣẹ takuntakun lori agbeyẹwo awọn orukọ naa gẹgẹ bi ilana ti Oludari Ile fun wọn.
Oludari Ile naa, Aṣofin Ọbasa tọka si ipele keji-le-mejilel-aadọwa (192) (Apa keji) Ori kẹfa iwe ofin orilẹ-ede Naijiria ọdun 1999 (gẹgẹ bi atunṣe rẹ) fun fifọwọ si awọn orukọ naa. Lẹyin eyi ni awọn awọn ọmọ egbẹ Ile Aṣofin naa wa fi ohun ṣọkan lati fi dibo ṣe atilẹyin fun yiyan awọn eniyan naa si ipo ijọba yii.
Leave a Reply