Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó kí Gómìnà Sanwó-Olú kú oríire ìdájọ́ tó ṣègbè fún un

Wọ́n pè fún àwọn àtúnṣe sí Òfin Ètò Ìdìbò

0 286

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ki Gomina Babajide Sanwo-Olu ati igbakeji rẹ, Ọmọwe Ọbafẹmi Hamzat ku oriire ajaṣẹgun wọn ni Ile-ẹjọ-ko-tẹ-mi-lọrun fun eto idibo gomina Ipinlẹ Eko ti ọdun 2023 to gbe wọn wọle.

Awọn aṣofin naa tun da a labaa pe, ki wọn ro igbimọ igbẹjọ pataki kan lagbara, ti yoo moju to awọn kudiẹ-kudiẹ ti wọn ṣakiyesi ninu eto idibo to kọja.

Nigba ti o mẹnu ba ọrọ naa ninu ipele ijiroro Alaye ara ẹni ninu gbọ̀ngàn Ile Aṣofin naa, Aṣofin Ọladipọ Ajọmale, ti o jẹ Alaga Igbimọ fun Eto Idajọ, Ẹtọ Ọmọniyan, Ifẹhonu-han ara ilu ati Eto Idibo Ijọba Ibilẹ (LASEIC) ninu Ile Aṣofin naa, gboriyin fun Ile Aṣofin Apapọ fun igbesẹ ṣiṣe ipade awọn alẹnulọrọ kaakiri orilẹ-ede yii ti wọn fẹ gbe lati fun awọn tọrọ kan lanfani lati fẹnu kun atunṣe si ofin eto idibo orilẹ-ede yii

Aṣofin Ajọmale woye pe, lara awọn ohun ti wọn ṣakiyesi ninu eto idibo to kọja naa ni ọrọ iforukọsilẹ awọn ondibo ati igba to n waye. O ni:

“Ile Aṣofin Apapọ ni lati ri i daju pe, akoko ti eto idibo fi n waye ko pẹ ju bo ṣe yẹ lọ.”

Bakan naa ni o tun mu u wa gẹgẹ bi aba pe, ko yẹ ki wọn yọ Ile-ẹjọ Ijọba Apapọ kuro ninu awọn ile-ẹjọ ti yoo maa ṣe ipinnu ọrọ eto idibo. O ni:

“Ninu Ofin Eto Idibo, o yẹ ki wọn ro awọn ile-ẹjọ giga ipinlẹ naa lagbara lati le gbẹjọ eto idibo.”

Ninu aba tirẹ, Asọfin Gbọlahan Yishawu, gboriyin fun igbesẹ ṣiṣe atunṣe si Ofin Eto Idibo yii. O ni:

“Mo gboriyin fun Ile Aṣofin Agba lati lero iru igbesẹ yii, pe, o yẹ ki awọn ara ilu le ni ipa ati oju-iwoye wọn si Ofin Eto Idibo odun 2022 yii.”

Aṣofin Aro Moshood naa da a labaa pe, ki Ajọ Eleto Idibo orilẹ-ede yii (INEC) gbaradi daadaa fun eto idibo to n bọ, ki Ile Aṣofin Apapọ si ṣe ilanilọyẹ gbogbo to yẹ lori ipade gbogboogbo awọn alẹnulọrọ yii.

Ninu ọrọ Aṣofin Noheem Adams, Olori Omo ẹgbẹ Oṣelu to pọ julọ ni Ile Aṣofin Eko, o woye pe ki wọn ṣe adinku si ọjọ ti ipolongo ibo fi n waye si oṣu meji lati oṣu marun-un to wa tẹlẹ ninu ofin naa.

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa, ẹni ti igbakeji rẹ, Aṣofin Mojisọla Meranda ṣoju fun ninu ijiroro naa sọ pe, ki Ajọ Eleto Idibo (INEC) maa ri daju pe, awọn igbese to yẹ ninu eto idibo n waye loorekoore. O ni:

“Ẹnikẹni ti o ba lẹtọọ ki o dibo ninu eto idibo ti yoo ba waye, wọn ko gbọdọ fi ẹtọ rẹ dun un. Awọn igbesẹ to ba yẹ gbọdọ bẹrẹ ni bayii, ki gbogbo ẹni to yẹ le kopa ninu rẹ.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button