Àjọ JAMB Fọwọ́sowọ́pọ̀ Pẹ̀lú Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Fún Ìwádìí Lórí Ìgbaniwọlé Lọ́nà Àlùmọ̀kọ́rọ́yí Ní Àwọn Ilé Ìwé Gíga
Àjọ JAMB ti fi ọwọ́ sí ìpinnu Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin láti se ìwádìí ìgbaniwọlé lọ́nà tí kò tọ́ ní àwọn Yunifásitì Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lójúnà àti sàfọ̀mọ́ àjọ náà
Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin fi ẹnu kò ní Ọjọ́bọ̀ láti se ìwádìí lórí ẹ̀sùn ìgbaniwọlé lọ́nà àìtọ́ lẹ́yìn ìgbà tí Sẹ́nétọ̀ Onyeka Nwebonyi tí ó sojú fún Arewa Ebonyi gbé àbá náà síwájú gbogbo ilé.
Nwebonyi sàlàyé wàhálà tí ó ń sẹlẹ̀ ní Yunifásitì Orílẹ̀-èdè Nàìjíría,̀ Nsukka níbi tí ìgbaniwọlé Chinyere Ekwe ti dá wàhálà sílẹ̀. Ó wá pàrọwà sí ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin fún ìdájọ́ òdodo léyìí ti o sapejuwe Ajọ JAMB gẹge bi eyi ti o duro déédé.
Leave a Reply