Ìjọba Ìpínlẹ̀ Sokoto ti fi ìgbáradì rẹ̀ léde láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn àjọ aládàníi lójúnà àti mú ìdàgbàsókè bá ètò ìlera alábọ́dé jákè-jádè ìpínlẹ̀ náà.
Gómìnà Ahmed Aliyu sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń se ìfilọ́lẹ̀ ètò àtúnṣe ilé ìwòsàn alábọ́dé mọ́kànlá ní Ìpínlẹ̀ Sokoto
Kíkọ́ àti àtúnṣe àwọn ilé ìwòsàn náà yóò wáyé ní ìjọba ìbílẹ̀ méje pẹ̀lú ìkúnlọ́wọ́ àjọ kan tí kìí se ti ìjọba (Plan International). Ètò náà wà ní ìbámu pẹ̀lú àlàkalẹ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ náà láti mú ìdàgbàsókè bá ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Sokoto.
Leave a Reply