Take a fresh look at your lifestyle.

Ìgbìmọ̀ fún Ètò Ìrìnnà Ọkọ̀ nínú Ilé Aṣòfin Èkó ṣe ìpàdé mọ̀mí-n-mọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ Ilé-iṣẹ́ Ìjọba fún Ètó Ìrìnnà Ọkọ̀ Ìpínlẹ̀ Èkó

0 161

Alaga Igbimo fun Eto Irinna Ọkọ ninu Ile Aṣofin Eko, Aṣofin Adewale Temitọpẹ Adedeji ti fi ipinnu rẹ mulẹ lati ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu Ile-iṣẹ Ijọba fun Eto Irinna Ọkọ ni Ipinlẹ Eko.

Aṣofin Adewale sọrọ yii nibi ipade mọmi-n-mọọ ti igbimọ naa ṣe pẹlu awọn oṣiṣẹ ẹka Eto Irinna Ọkọ Ipinlẹ Eko ni ọjọ Ẹti (Friday)

Ninu ọrọ rẹ, Aṣofin Adewale sọ pe, laipẹ, Ile Aṣofin naa yoo fi iwe pe wọn lati jọ forikori lori awọn ọna lati fi yanju awọn iṣoro to n koju ẹka Eto Irinna Ọkọ ni Ipinlẹ yii. O ni:

“Eleyii ti a ṣe ni oni ni lati ṣe agbekalẹ igbimọ, ki a si fi mọ ara wa ni Ile-iṣẹ Eto Irinna Ọkọ, awọn ajọ ati awọn ẹka ile-iṣẹ ijọba to nii ṣe pẹlu eyi. Ile-iṣẹ Eto Irinna Ọkọ ni ojuṣe lati ri i daju pe irinkerindo awọn olugbe Ipinlẹ Eko jẹ irọrun. Awọn eleyii ti a jiroro le lori loni jẹ eyi ti a gbọdọ wa ojutu si loju ẹsẹ. Laipẹ, a o pe yin lati wa jọ forikori lori awọn ipenija yooku gẹgẹ bi awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin yii ṣe ṣakiyesi wọn.”

Aṣofin naa tun fi kun ọrọ rẹ, pe oun ni ireti lati ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu Alakoso-agba fun Eto Irinna Ọkọ ati awọn alaṣẹ yooku ni ẹka yii. O ṣalaye pe, iṣẹ pọ ti igbịmọ naa yoo ṣe, ati pe, pẹlu ifọwọsowọpọ Alakoso-agba naa, gbogbo rẹ ni awọn yoo ṣe pẹlu irọrun. O ni:

“Tootọ ni pe, a ni iṣẹ to pọ lati ṣe, ṣugbọn pẹlu Alakoso-agba, ẹni ti o ni oye kikun nipa iṣẹ yii, yoo rọrun fun wa lati ṣe. Pẹlu ipade yii, a ti mọ pe, Ile-iṣẹ Ijọba fun Eto Irinna Ọkọ yii ti ṣetan lati ṣiṣẹ, ti wọn si gbero lati tẹle awọn ofin ati ilana atunṣe ati atunto ẹka eto Irinna Ọkọ ki awọn ara ilu le jere eto ijọba Tiwa-n-tiwa gẹgẹ bi ohun ti Oludari Ile-Aṣofin yii, Aṣofin Mudashiru Ọbasa maa n tẹnu mọ ni gbogbo igba.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button