Ìpínlẹ̀ Èkó kò ní wó ilé láìṣe pé, wọ́n ṣe gbogbo nǹkan tó yẹ- Ilé Aṣòfin Èkó fi dá àwọn olùgbé lójú
Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti fi da awọn ara ilu loju pe, awọn ko le wo ile ẹnikẹni laiṣe pe wọn san awọn owo ti o yẹ fun oni-nnkan; boya fun kikọ oju ọna tabi fun awọn iṣẹ idagbasoke miiran.
Oludari Ile Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa lo sọrọ idaniloju yii nigba ti o n ba awọn onile ati olugbe agbegbe Owutu ni agbegbe Agric ni Ilu Ikorodu ti wọn ṣe ifẹhonu-han wa si gbagede Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko lọjọBọ Thursday sọrọ. Eleyii ni ifehonuhan ti wọn fi n tako igbesẹIle-iṣẹ ijọba fu Ile kikọ ni Ipinlẹ Eko lati tun wo awọn ile wọn ni igba keji laarin ọdun marun-un nitori ọna Owutu si Isawo si Arepo ti wọn n ṣe lọwọ.
Aṣofin Ọbasa, ẹni ti Aṣofin Bonu Solomon (Aṣoju ẹkun idibo Badagry kinni) ṣoju fun, pẹlu awọn aṣofin mẹwaa miiran nikalẹ dupẹ lọwọ awọn olugbe agbegbe naa fun titẹle ilana to tọ lati fi ẹdun ọkan wọn han, ati pe, Ile Aṣofin naa yoo gbe igbesẹ to tọ lori ọrọ naa.
Awọn olugbe Owutu ti wọn gbe ifẹhonuhan wọ Ile Aṣofin naa ni wọn pọ niye, ti ọpọ awọn agbalagba lọkunrin, lobinrin ati ọdọ wa ninu wọn. Wọn wa rọ Ile Aṣofin naa ki wọn tete gbe igbesẹ nitori ọjọ meje pere ni ijọba fun wọn lati kuro ni agbegbe naa laisi iwe ifitonleti kankan tẹlẹ.
Agbẹnusọ ikọ awọn olugbe Owutu naa, Ọgbẹni Ganiyu Mustapha to wa lori kẹkẹ alaabọ-ara, sọ pe, ọrọ naa n ba awọn lẹru nitori pe, awọn ti kọkọ mu awọn lẹta ifẹhonuhan bayii wa si Ile Aṣofin yii kan naa, lọ si ọfiisi Gomina ati Ile-iṣẹ Ijọba fun ọrọ Iṣẹ́-Ode ni ọjọ kẹta oṣu kẹjọ ọdun yii, ti awọn ko ri esi kankan gba. O ni afaimọ ni ko ma ṣe pe, awọn ti wọn wa nidii iṣẹ yii ni wọn ko fẹ ki lẹta ifẹhonuhan yii de ibi to yẹ.
Ọgbẹni Mustapha sọ pe, awọn aṣoju ẹkun Ikorodu yii, bii Aṣofin S.O.B Agunbiade, Aṣofin Tokunbọ Ogunlẹyẹ, Gomina Akinwunmi Ambode ati Gomina Babajide Sanwo-Olu to wa lori oye bayii, gbogbo wọn lo ti wa wo agbegbe naa ni ọpọ igba, ti wọn si n fi da wọn loju pe, iṣẹ ona naa ko le pa awọn ile wọnyi lara, ati pe, bi gbogbo rẹ ṣe wa yi pada bayii, jẹ ọrọ iyalẹnu fun wọn.
Baba agbalagba kan, Alhaji Mustapha Salami ti o gbẹnu awọn onile agbegbe naa sọrọ, o ni igbesẹ awọn Ile-iṣẹ ijoba fun ile kikọ ni Ipinlẹ Eko ati awọn ile-iṣẹ ti wọn gba iṣẹ akanṣe naa jẹ igbesẹ ti ko boju mu. O ni: “Nigba ti wọn wo awọn ile wa ni ọdun marun-un sẹyin, wọn la awọn ọna naa daradara, wọn si wo awọn opo ina, ti a si ko awọn awoku ile wa danu, ki a to pada lọ kọ awọn ile miiran sibi to yẹ. Ni bayii ti a ti na ọpọlọpọ owo, ti ọpọ ninu wa lọ yawo n banki, ti ẹlomiiran fọwọ sowọpọ pẹlu awọn abanikọle, ti wọn ti kọ ile alaja bii meji ati awọn ile itaja. Bawo lo wa se le ṣẹlẹ lojiji, ti ẹ o sọ pe, ki a tun gbe ile wa kuro pe, ẹ fun wa ni gbedeke ọjọ meje.”
Alagba Salami ti o ni ọrọ naa ti da aisan si oun lara lati igba ti oun ti gbọ irọyin naa, sọ pe iru igbesẹ yii buru jai. O wa rawọ ẹbẹ si Ile Aṣofin naa lati ba awọn da si ọrọ naa.
Aṣofin Solomon tun tẹnu mọ ileri rẹ pe, Ile Aṣofin naa yoo tete gbe igbesẹ to yẹ lori ọrọ naa, ati pe ko si bi ẹni kan ṣe le lagbara to ti yoo fi ipo rẹ yan wọn jẹ ni Ipinlẹ Eko yii.
Leave a Reply