Ilé Aṣòfin Èkó ṣe ìrántí àyàjọ́ àwọn alárun ọpọlọ lágbàáyé
Wọ́n pè fún pípèsè ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn fún àrùn ọpọlọ
Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ṣe iranti ayajọ awọn alarun ọpọlọ lagbaaye.
Aba lati ṣe iranti ayajọ awọn alarun ọpọlọ lagbaaye yii ni Aṣofin Aina Musibau mu wa, pe ọjọ kejila oṣu kẹwaa ọdun ni wọn ya sọtọ lagbaaye lati fi ṣe ilanilọyẹ, lati ni imọ ati lati ṣe idanimọ itọju fun arun ọpọlọ.
Aṣofin Lukman Olumoh ṣalaye pe ohun ti o n ṣokunfa arun ọpọlọ lọpọ igba ni ilokulo oogun, lilo oogun oloro ati arokan ti o n mu ibanujẹ ọkan wa. O wa pe ijọba lati pese ọpọ iru ile-iwosan bayii ti yoo maa toju awọn alarun ọpọlọ.
Aṣofin Tijani Suraj rọ awọn obi lati maa kilọ fun awọn ọmọ nipa ipalara ilokulo oogun oloro loorekoore.
Aṣofin Adebọla Shabi rọ awọn obi lati maa ba awọn ọmọ wọn sọrọ iṣiti, paapaa awọn ọmobinrin ti wọn maa n fe ṣera wọn leṣe bi ololufẹ wọn ba sọ pe awọn ko ṣe mọ, ti eyi si sabaa maa n ja si arun ọpọlọ fun wọn. Ki awọn ajọ alaanu loriṣiriiṣi wa ti yoo maa la awọn eniyan lọyẹ nipa arun yii, ti yoo si le maa ṣe itọju wọn. Ki awọn olori ati aṣiwaju maa sọrọ ifnilọkan balẹ fun awọn ara ilu pe, ọrọ-aje to le koko yii yoo si dẹrọ laipẹ laijina.
Aṣofin Stephen Ogundipẹ rọ ijọba lati tubọ pese ohun elo iranwọ fun adinku ipalara ọrọ-aje to le koko bayii. Ki ijọba, lọbalọba ati awọn Baalẹ maa sọrọ kori-o-ya fun awọn ara ilu pe, ohun gbogbo yoo dẹrọ.
Gbogbo awọn Aṣofin to da si ọrọ naa ni wọn rọ ijọba lati pese ọpọ ile-iwosan fun awọn alarun ọpọlọ, ki wọn gba awọn dokita, awọn olutọju ati nọọsi to to fun wọn.
Ile Aṣofin naa labẹ Igbakeji Oludari Ile, ti o dari ijokoo naa, Aṣofin Mojisọla Meranda fẹnu ko pe, agbegbe ijọba ibilẹ kọọkan ni lati ni awọn agbaninimọran pataki ni awọn ile-iwosan alabọde (PHC), tori ki i ṣe gbogbo awọn alarun ọpọlọ lo nilo lati lọ si ile-iwosan nla.
Lẹyin eyi ni Ile Igbimọ Aṣofin naa fọwọ si abajade igbimọ tẹẹkoto lori iwadii ọmọkunrin, Adebọla Akin-Bright, ti ifun rẹ sọnu nigba ti wọn n ṣe iṣẹ abẹ fun un, ti ọmọ naa si ku nigbẹyin.
Leave a Reply