Ilé Aṣòfin Èkó ṣe àjọyọ̀ Ọjọ́ àwọn ọmọbìnrin lágbàáyé
Wọ́n pè fún fífi ọwọ́ ọkúnkúndùn mú àmójútó ọmọbìnrin
Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ṣe ajọyọ Ọjọ awọn ọmọbinrin lagbaaye.
Aba lati ṣe ajọyọ Ọjọ awọn ọmọbinrin lagbaaye yii ni Aṣofin Ọmọbabirin Ọmọlara Lawal-Olumẹgbọn, ti o jẹ Alaga fun Igbimọ to n moju to Ọrọ Obinrin, Iṣadinku Ìṣẹ́ ati Ipese Iṣẹ́ ninu Ile Aṣofin naa mu wa.
O woye pe, ọjọ kọkanla oṣu kẹwaa ọdun ni wọn fi n ṣe iranti awọn ẹtọ ọmọbinrin, ipenija ati riro wọn lagbara fun ọrọ aje lagbaaye.
Aṣofin Olumẹgbọn woye pe, ijọba Ipinlẹ Eko ti ṣe agbekalẹ ofin to nii ṣe pẹlu iwa ipa laarin inu ile ati ifipabanilopọ lawujọ, iyẹn ‘Lagos State Domestic and Sexual Violence Law’ to fun awọn ọmọbinrin lẹtọọ kan naa, paapaa eyi to tako iwa ifpabanilopọ ati awọn iṣeniniṣekuṣe miiran.
Ninu ọrọ rẹ, Aṣofin Lukman Olumoh sọ pe, bo tilẹ ṣe pe ijọba n sapa pẹlu gbogbo akitiyan lati daabo bo awọn ọmọbinrin, sibẹ awọn kan si n lo wọn nilokulo, ti wọn n ko wọn lọ ṣowo ẹru.
Ẹwẹ, o gboriyin fun Aarẹ Tinubu fun ipo minisita ati awọn ipo miiran loriṣiiriṣi to fun awọn obinrin ninu ijọba rẹ.
Aṣofin Nureni Akinsanya rọ awọn obi lati maa fi aaye silẹ lati fi kọ awọn ọmọ wọn ni iwa ọmọluabi.
Aṣofin Aro Moshood pe fun eto ilanilọyẹ loriṣiriiṣi lori ẹrọ ayelujara, tẹlifiṣọn ati radio lati maa fi tako iwa ilokulo oogun laarin ọdọ.
Aṣofin Fẹmi Saheed ninu ọrọ rẹ mẹnu ba ọpọlọpọ awọn akikanju obinrin lorilẹ-ede Naijiria bi aya Aarẹ, Aṣofin Olurẹmi Tinubu, Arabinrin Funmilayọ Ransome-Kuti, Alhaja Abibat Mogaji ati awọn miiran bẹẹ ti wọn fun lẹkọọ to ye kooro lati gbe ogo orilẹ-ede yii ga. O ni’ “ẹnikẹni ti o ba kọ ọmọbinrin lẹkọọ to ye kooro, o ti kọ odiidi orilẹ-ede kan.”
Aṣofin Mosunmọla Sangodara rọ awọn obi lati maa ṣe amojuto awọn ọmo daradara. O wa rọ awọn baba lati ma fi ọrọ imojuto ọmọ da iya nikan ninu ile. Bẹẹ lo pe awọn agbofinro lati fọwọ okunkundun mu ọrọ iwa kiko awọn obinrin lọ ṣowo ẹru.
Igbakeji Oludari Ile, ti o dari ijokoo naa, Aṣofin Mojisọla Meranda naa woye pe, riro awọn obinrin lagbara fun ọrọ aje ṣe pataki, nitori “bi a ba ti ro ọmọbinrin kan lagbara a ti ro odiidi orilẹ-ede kan lagbara fun ọrọ-aje “.
Aṣofin Meranda wa fi kun ọrọ rẹ pe, ọrọ yii ko yọ awọn ọmọkunrin silẹ, nitori bi a ba kọ wọn lọna to tọ, wọn ko ni le maa lọwọ ninu iwa ṣiṣe obinrin niṣekuṣe.
Leave a Reply