Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn alẹ́nulọ́rò gbóríyìn fún Ilé Aṣòfin Èkó lórí ìwádìí wọn nípa ọmọ tí ìfun rẹ̀ sọnù lásìkò iṣẹ́ abẹ

0 252

Wọn ti gboriyin fun Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko labẹ Oludari Ile, Aṣofin Mudashiru Ọbasa fun igbese iṣẹ iwadii wọn nipa Ọmọdekunrin Adebọla Akin-Bright ti o ku latari ara ifun rẹ ti o sọnu ni asiko ti wọn n ṣiṣe abẹ fun un ni ile-iwosan.

Nibi ipade awọn tọrọ kan gbogbo lori ọrọ naa ni Alakoso-agba fun Eto Ilera ni Ipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi, awọn aṣoju Ẹgbẹ Dokita ni orilẹ-ede Naijiria, ẹka ti Ipinlẹ Eko, awọn aṣoju Ẹgbẹ awọn Ile-iwosan Aladani ni Ipinlẹ Eko ati awọn alẹnulọrọ miiran ti gboriyin fun ilana iṣewadii Ile Asofin naa lori aṣiṣe awọn ile-iwosan to lọwọ ninu itọju ọmọde naa, Oloogbe Adebola Akin-Bright.

Ẹwẹ, awọn tọrọ kan ti wọn wa nibi ipade itagbangba naa lo mu imọran ati akiyesi wọn wa lori ọrọ iṣẹ iwadii naa.

Lara awọn to wa nibi ipade itagbangba naa ni Dokita Abayomi Baiyewu ti ile-iwosan Obitoks ti o ṣe isẹ̣ abẹ lẹẹmeji fun ọmọ naa ki wọn to gbe e lọ si Ile-Iwosan Akoṣẹmọṣẹ Ipinlẹ Eko, iyen LASUTH.

Ta o ba gbagbe, Ẹgbẹ awọn Ile-iwosan Aladani orilẹ-ede Naijiria, iyen ‘ANPMP’ ti fẹsun kan Ile Aṣofin naa pe, wọn mọọmọ fẹ fi iwadii wọn dọde Dokita Baiyewu ni pelu eleyii ti wọn lọ ṣe pẹlu rẹ laisi awọn tọrọ kan nibẹ. Eleyii ni o ṣokunfa iwadii itagbangba naa ti wọn ti pe awọn alẹnulọrọ gbogbo, ti wọn ti ṣafihan fọnran ti wọn fi ṣe iwadii fun Dokita Baiyewu.

Ninu fọnran amohunmaworan naa ni Dokita Baiyewu ti gba pe, oun yọ apa kan lara ifun Oloogbe Akin-Bright nigba ti wọn n ṣe iṣẹ abẹ fun un, ti awọn si fi aṣiṣe da wọn nu dipo ki awọn mu wọn lọ fun ayẹwo gẹgẹ bi ofin ati ilana iṣẹ dokita. Iwadii naa tun fi han pe ile-iwosan ‘Obitoks’ ko lo awọn olutọju alaisan akọṣẹmọṣẹ, dipo bẹẹ, awọn nọọsi ‘muyiwa’ ni wọn lo fun iṣẹ abẹ naa.

Dokita Baiyewu si fi mule pe, lootọ ni pe, oun loun sọ gbogbo ọrọ ori fọnran naa.

Lẹyin ti wọn wo fọnran naa tan, Alakoso-agba fun Eto Ilera naa, Ọjọgbọn Abayọmi sọ pe, iṣẹ iwadii to poju owo ni Ile Aṣofin naa ti se lori ọrọ naa, ati pe, Ile-iṣẹ Ijọba fun Eto Ilera ni Ipinlẹ Eko ti ti ibi iṣiṣe abẹ ile-iwosan ‘Obitoks’ naa pa, pe ko tọna fun iṣẹ abẹ. O ṣalaye pe nigba ti won fi maa gbe Omodekunrin Akin-Bright de Ile iwosan LASUTH, alaafia ara rẹ ti mẹhẹ, wọn si ni lati da okun pada si ara rẹ ki wọn to ṣe ise abẹ miiran fun un nibẹ. Ni asiko ti wọn pada fẹ se ise abe naa ni won sakiyesi pe, ko si ifun kekere kan ninu ifun ọmọ naa mọ, eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ, nitori ifun naa ṣe pataki fun igbesi aye ẹda. O ni:

“Ohun ti a ṣakiyesi ni pe, Dokita Baiyewu ti ṣe iṣẹ abẹ meji fun ọmọdekunrin naa, o si ti yọ lara ifun kekere ọmọ naa kuro. O ṣe e ṣe pe, ni asiko yii o ti ṣe ipalara fun bi ẹjẹ ṣe n wọle si ẹya ara naa, eleyii ti ifun kekere naa yoo ti maa baje, ti yoo fi parẹ mọ awọn yooku lara.”

O ni awọn ti fi abajade iwadii awọn ṣọwọ si Igbimọ Alaṣe fun Ọrọ awon Dokita ni orile-ede yii, iyen MDCN fun ṣiṣe iwadii siwaju ati lati gbe igbesẹ ijiya to ba tọ lori ọrọ naa.

Dokita agba naa woye pe, ijọba ti gbiyanju lori ọrọ Akin-Bright ti awọn naa ti lọ sọdọ rẹ pẹlu ileri ijọba Ipinlẹ Eko pe, wọn yoo gbe e lo si ilu oyinbo lati tete lọ se iṣẹ abẹ ti wọn yoo fi da ifun naa pada, ki o to wa ku lọrọ ẹyin. Sibe iwadii si n lọ lowo gege bi Ile Aṣofin yii ṣe ṣe agbatẹru rẹ lati ṣe iwadii okodoro ọrọ ti awọn si ti gbe awọn abajade tiwọn lo sọdọ Igbimọ Alaṣẹ awọn Dokita orilẹ-ede Naijiria lati gbe igbesẹ to tọ.

 

Ninu ọrọ rẹ, Dokita Kayọde Akinlade, Alaga tẹle fun Ẹgbẹ awọn Dokita, ẹka ti Ipinle Eko, dupẹ lọwọ Ile Aṣofin yii fun iwadii kikun naa, ati pe ọpọ awọn Dokita aladani maa n wo oju ti awọn ara ilu fi n wo iṣẹ wọn ni.

Dokita Benjamin Olowojẹbutu, Alaga Ẹgbẹ awọn Dokita, ẹka ti Ipinlẹ Eko, fi kun ọrọ naa pe gbogbo iwadii awọn tọrọ kan ni awon fara mọ, ti wọn yoo si gbe igbese to tọ, to ba ya.

Igbimọ Tẹẹkoto ti Ile Aṣofin Eko yan lati ṣe iwadii naa, labẹ Alaga wọn, Aṣofin Noheem Adams, Olori Omo egbe oselu to po julo ninu Ile Asofin Eko n beere ọrọ lọwọ awọn tọrọ kan naa lọlọkan-o-jọkan lati fi ododo ọrọ mulẹ. Aṣofin Adams wa dupẹ lọwọ awon olukopa yii, pẹlu ileri lati jabo ̣iwadii naa fun Oludari Ile, Aṣofin Ọbasa ati Ile lapapọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button