Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Tinubu ti fi ẹsẹ̀ ọrọ̀-ajé orílẹ̀-èdè yìí lé ojú ọ̀nà rere – Aṣòfin Ọbasá

0 190

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti ṣapejuwe ijọba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti orilẹ-ede Naijria lati igba ti wọn ti dori aleefa gẹgẹ bi eyi ti o n fi ẹsẹ ọrọ-aje orilẹ-ede yii si oju ọna rere.

Aṣofin Ọbasa sọrọ yii ninu ọrọ ikini rẹ fun ajọdun ominira kẹtalelọgota ti orilẹ-ede Naijiria. O ṣalaye pe, Aṣiwaju Tinubu mọ apade ati alude ọrọ-aje, ti yoo le mu orilẹ-ede yii de ebute ayọ

Ninu iwoye rẹ si ipenija ti orilẹ-ede Naijiria n koju bayii, Aṣofin Ọbasa rọ awọn ara ilu lati ni amumọra pẹlu ọpọ suuru, pẹlu igbagbọ pe, orilẹ-ede yii yoo de ebute ogo laipẹ yii. O ni:

“Gbogbo wa la mọ bi nnkan ṣe ri bayii ni orilẹ-ede yii. A si mọ ohun ti ẹni kọọkan wa n fara da lati ri i daju pe, nnkan pada bọ sipo. A si dupe bayii pe, ijọba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti n gbe igbesẹ to nitumọ lati koju awọn ipenija, ati awọn eto ti ijọba naa n ṣe lati fi yanju awọn iṣoro naa. Iru olori bayii ni orilẹ-ede Naijirian nilo ni asiko yii.

“Orilẹ-ede Naijiria ti koju awọn ipele idagbasoke lati igba ti a ti gba ominira ni ọdun 1960. Eleyii si ti wa pẹlu ọpọ ipenija, eyi ti a fi n beere fun olori tootọ.

“Ẹwe, laarin oṣu diẹ bayii ijọba yii ti n gbe awọn igbesẹ, eleyii ti yoo fun wa ni abajade rere, ti a ti n foju sọna fun. Gbogbo wa la n fẹ orilẹ-ede ti yoo le jẹ korioya fun awọn olokoowo ni ilẹ okeere lati wa ṣe òwò; a n fẹ eto ilera ti yoo dara; a si n beere fun ẹkọ to ye kooro fun awọn ọmọ wa; ipese iṣẹ ati ohun amayedẹrun gbogbo. Gbogbo eleyii lo ṣe e ṣe, paapaa bi a ba fọwọ sowọpọ pẹlu ijọba to wa lori aleefa yii. Orilẹ-ede Naijiria ti wa lojuna si ebute ogo naa bayii. Ki a fi ẹmi aforiti, otitọ si ilu ẹni ati agbara wa mu eyi wa si imuṣẹ lo ku.

“Mo ki gbogbo ọmọ orilẹ-ede Naijiria ku oriire oni, mo si rọ wọn lati ni ireti ayọ fun ọjọ iwaju rere. Ni Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, a ti gbe awọn igbesẹ ti yoo mu ọjọ iwaju wa dara, paapaa lati fi mu eto aabo fẹsẹ mulẹ. A ko ni fọwọ lẹran wo lori awọn aṣeyọri yii, ṣugbọn a o ṣiṣẹ takuntakun lori rẹ lati jẹ ki awọn ara Ipinlẹ Eko gbagbọ ninu ipinlẹ yii ati awọn aṣeyọri rẹ.”

Alukoro-agba si Oludari Ile Aṣofin Eko, Ọgbẹni Eromosele Ebhomele lo gbe ọrọ ikini Oludari Ile naa jade.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button