Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó fọwọ́ sí Sule-Akibu fún ipò alákoso-àgbà ìlú

0 215

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti fọwọ si Ọgbẹni Tọlani Sule-Akibu gẹgẹ bi ọkan lara alakoso-agba jọba ti Gomina Babajide Sanwo-Olu fi ranṣẹ si wọn

Ọgbẹni Sule-Akibu wa lara awọn awọn orukọ alakoso-agba mejidinlogun ti Gomina fi ranṣẹ si Ile Aṣofin naa ninu ọsẹ to kọja.

Awọn aṣofin naa danu duro lori ọrọ rẹ ninu ijiroro ile lỌjọbọ Thursday to kọja nigba ti wọn ko le fẹnu ko boya ki wọn fọwọ si i fun ipo naa tabi bẹẹ ko.

Ẹwẹ, ninu ipade ijiroro Ile lỌjọ Iṣẹgun Tuesday, eyi ti igbakeji Oludari Ile Aṣofin naa, Aṣofin Mojisọla Meranda dari, ni wọn ti fọwọ si yiyan Ọgbẹni Sule-Akibu fun ipo alakoso-agba ipinlẹ yii lẹyin idibo ti wọn fi ohun ẹnu ṣatilẹyin fun.

Lẹyin eyi ni Aṣofin Meranda paṣẹ fun Akọwe-agba Ile Aṣofin naa, Amofin Ọlalekan Ọnafẹkọ lati kọwe ranṣe si Gomina, pe wọn ti fọwọ si Ọgbẹni Sule-Akibu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button