Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Gbóríyìn Fún Ààrẹ Tinubu Látàrí Ìfiléde Èyí Tí Ó Sàfihàn Ìdẹ̀kùn Tí Yóò Tọ́sí Ará Ìlú Látàrí Yíyọ Ìgúnpá Orí Epo
Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin ti gbóríyìn fún Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu fún ìfiléde rẹ̀ lórí ọ̀nà àti mú ìdẹ̀kùn bá ará ìlú látàrí ìlekoko tí yíyọ ìrànwọ́ orí epo dá sílẹ̀ láàrin àwùjọ
Agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin, Ọnọrébù Akin Rotimi ni ó se ìfiléde ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń fi ẹ̀dùn ọkàn hàn lórí ìnira tí ó n bá ará ìlú fínra látàrí yíyọ ìrànwọ́ orí epo, sùgbọ́n ó fi ìgbàgbọ́ hàn pé dídùn ní ọsàn yóò so, nítorí pé ìfiléde Ààrẹ fini lọ́kàn balẹ̀.
Ó wá fi ará ìlú lọ́kàn balẹ̀ pé, ilé ìgbìmọ̀ asofin yoo ri daju pe awọn ohun ìgbáyégbádùn naa yoo tẹ ara ilu lọwọ.
Leave a Reply