Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko rawọ ẹbẹ si awọn Ẹgbẹ Ayedaade Oṣiṣẹ, Nigerian Labour Congress (NLC) ati Trade Union (TUC) lati ma ṣe da iṣẹ silẹ gẹgẹ bi ipinnu wọn.
Akọwe-agba Ile Aṣofin naa, Amofin Ọlalekan Ọnafẹkọ lo rawọ ẹbẹ yii. O ni ki awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ro ipalara ti iyanṣẹlodi naa yoo ko ba awọn ara ilu, pẹlu eleyii ti wọn foju wina tẹlẹ.
Akọwe-agba Ile Aṣofin naa, ẹni ti o sọrọ yii nibi ipade idanilẹkọọ kan ti wọn ṣagbatẹru rẹ fun awọn oṣiṣẹ Ile Igbimọ Aṣofin ati awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Ipinlẹ Eko, woye pe ipalara ijọba ologun ki i ṣe kekere lara awọn ara ilu lorilẹ-ede kan.
O wa rọ awọn aṣiwaju Ile Igbimọ Aṣofin Apapọ lati tẹ siwaju fun idanilẹkọọ awọn oṣiṣẹ wọn lati le ni aṣeyọri fun erongba ti wọn fi da Ile Aṣofin naa silẹ. O ni:
“Ṣiṣe idiwọ fun eto ijọba tiwa-n-tiwa lorilẹ-ede Naijiria ti mu ifaseyin ba idagbasoke ẹka Ile Aṣofin, ni ti ijọba Apapọ ati ti Ipinlẹ. Fun idi eyi fifun awọn oṣiṣẹ ni ẹka Ile Aṣofin ni orilẹ-ede Naijiria ni idanilẹkọ deedee ṣe pataki, nitori eyi ni ẹka ti wọn ki i ṣamulo mọ paapaa ti ologun ba gba ijọba. Ni gbogbo asiko yii, awọn oṣiṣẹ lẹka Amuṣẹṣe ati ẹka Idajọ si le ni anfani si idanilẹkọọ loorekoore.”
O tun bẹ awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lati gegi dina iyanṣẹlodi ti wọn fẹ gun le, ki wọn le fun ijọba apapọ lanfani lati le forikori pẹlu wọn, ki wọn fẹnu ko sibi to yẹ.
Nigba ti o n gboriyin fun Ile Aṣofi Apapọ fun akitiyan wọn lati fi kun imọ awọn oṣiṣẹ wọn, Amofin Ọnafẹkọ fi mulẹ pe,
“Awọn oṣiṣẹ ni ogún pataki ni ile-iṣẹ tabi ajọ kan, bi a ba ṣe n fun wọn ni imọ bayii, atubọtan rẹ yoo mu aṣeyọri ati idagbasoke ba ile-iṣẹ/ajọ bẹẹ.”
O ni iru idanilẹkọọ bayii yoo mu igberu ba agbọye laarin ijọba ati awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ, ti awọn oṣiṣẹ to kopa ninu rẹ yoo le lo o lati fi mu igberu ba iṣẹ wọn.
Leave a Reply