Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó tẹnu mọ́ pàtàkì ṣíṣe ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀

0 165

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti tẹnu mọ pataki ṣiṣe idasilẹ ọlọpaa Ipinlẹ lati le gegi dina bi wọn ṣe n pa awọn eniyan nipakupa ati awọn ipenija aabo lawujọ paapaa Ipinlẹ Eko.

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ninu ijokoo Ile Aṣofin naa lỌjọ Iṣegun (Tuesday) nigba ti o bẹnu atẹ lu bi awọn kan ṣe pa ọpọ eniyan ni Ipinlẹ Plataeu, o ṣalaye pe, ṣise idasilẹ Ọlọpaa Ipinlẹ ṣe pataki ni asiko yii lati dena awọn iwa ọdaran naa ni Ipinlẹ Eko.

O rọ Ile Igbimọ Aṣofin Apapọ lati bẹrẹ agbeyẹwo iwe ofin ti yoo fi faaye gba idasilẹ Ọlọpaa Ipinlẹ.

Nigba ti o n fi aba ṣiṣe idasilẹ Ọlọpaa Ipinlẹ naa mulẹ, Olori ọmọ ẹgbẹ Oṣelu to pọ julọ ninu Ile Igbimọ Aṣofin naa, Aṣofin Naheem Adams rọ Ile Aṣofin Apapọ lati fọwọ ọkunkundun mu idasilẹ Olọpaa Ipinlẹ nitori o ṣe pataki pupọ fun idokoowo laarin ilu. O ni:

“Awọn ọlọpaa ipinlẹ yoo ṣadinku pipa eniyan nipakupa ati mimu awọn awọn eniyan nigbekun. A pe Aarẹ Ile Aṣofin agba ati Oludari Ile Igbimọ Aṣojuṣofin lati karamaasiki ọrọ idasilẹ Ọlọpaa Ipinlẹ ni kia”

Aṣofi Gbọlahan Yishau to ń ṣoju ẹkun idibo Eti Ọsa keji ninu Ile Aṣofin naa sọ pe, awọn ọlọpaa ijọba apapọ nikan ko le koju awọn ipenija eto aabo mọ. O ni:

“A ranti pe, ẹyin (Oludari Ile) naa lẹ ṣe agbatẹru idasilẹ ẹṣo aabo abẹle ti Ipinlẹ Eko, ‘LNSC’. Ẹ si ti n tẹmọ ṣiṣe idasilẹ Ọlọpaa Ipinlẹ yii. Ọrọ ipenija yii n fara han ni gbogbo igba, ti wọn ko ri nnkan ṣe si i. Aarẹ Tinubu ti n gbiyanju lati da nnkan pada sipo lorilẹ-ede yii, ṣugbọn ki ọrọ-aje le fẹsẹ mulẹ a nilo eto aabo to fẹsẹ mulẹ. Awọn ọlọpaa ti a ni bayii ko to nnkan. Ọlọpaa ijọba apapọ nikan ko le to. O yẹ ki ọlọpaa wa kaakiri agbegbe wa naa.”

Aṣofin David Setoji to n ṣoju ẹkun idibo Badagry keji, gboriyin fun Oludari Ile Aṣofin naa fun iṣẹ akikanju rẹ lati ṣiwaju awọn ọrọ to kan ara ilu gbọngbọn. O ni:

“Ẹ maa n ṣiwaju awọn ọrọ ti yoo ni ipa rere lara awọn ara Ipinlẹ Eko. Bi a ba ranti awọn ti wọn pa ni agbegbe Ajah, Bọlanle Raheem ati Jafar Buraimoh. Bi o ba ṣe pe Ipinlẹ Eko ni Ọlọpaa ipinlẹ ni, iru eyi ko ni waye. Ki la ti n gbọ, ki gbogbo ọlọpaa to wa ni Ipinlẹ Eko yii ma to ẹgbẹrun lọna igba (200,000). Gbogbo orilẹ-ede ni wọn ti n ni ọlọpaa agbegbe, ki lo de ti tiwa fi yatọ?”

Aṣofin Fẹmi Saheed to n ṣoju ẹkun idibo Koṣofẹ keji sọ pe, “Ile Aṣofin kẹwaa yii ní lati tete ṣiṣẹ lori idasilẹ Ọlọpaa Ipinlẹ. Bi a ba fẹ ki ọro-aje fẹsẹ mule a ni lati kọkọ mu lele eto aabo.”

Aṣofin Richard Kasumu ni tirẹ sọ pe, “ọrọ ṣiṣe idasilẹ Ọlọpaa Ipinlẹ ko ni ariyanjiyan ninu mọ. Ọrọ ipenija aabo ti n pẹ ju, ninu eyi ti a n fi ẹmi awọn eniyan sinu ewu. A rọ Ile Igbimọ Aṣofin agba lati tete ṣiṣẹ lori idasilẹ ọlọpaa Ipinlẹ ki iṣẹ idaabo bo ilu le ni aṣeyọri. Bo tilẹ jẹ pe, Aarẹ funra wọn ti ṣe ileri lati ṣe agbeyẹwo ọrọ naa, a si tun n bẹbẹ lati fun Ipinlẹ Eko ni ẹtọ pataki.”

Lara awọn ọmọ ẹgbẹ aṣofin ti wọn tun sọrọ lati fi gbe aba yii lẹyin ni Aṣofin Akanbi Oluwa ati Aṣofin Desmond Eliot.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button