Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàíjíríà ní láti mọ rírì iṣẹ́ àti ìrírí àwọn aṣòfin – Aṣòfin Agúnbíadé

0 218

Olori ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ ju lọ ana ninu Ile Igbimọ Aṣofin Eko, Aṣofin Sanai Oyeniran Agunbiade, ti ọpọ mọ si S.O.B ti rọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati maa wo pataki iriri lẹka ijọba aṣofin ilu.

Aṣofin Agunbiade ti o ṣoju ẹkun idibo Ikorodu kinni ninu Ile Aṣofin naa lati ọdun 2007 si 2023 sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnu-wo rẹ pẹlu awọn oniroyin ninu ọfiisi rẹ ni Ile Aṣofin naa laipẹ yii. O ni bi awọn aṣofin ba ṣe n pẹ si lẹnu iṣẹ aṣofin ni wọn yoo fi maa kopa ribiribi fun ilọsiwaju ilu, nigba ti o sọ pe, gbogbo asiko ti oun lo lẹnu iṣẹ naa ni oun gbadun. O ni:

“Mo fẹran iṣẹ aṣofin, gbogbo ọjọ ti mo si lo ninu Ile Aṣofin yii ni mo gbadun. O kan ṣe ni laanu pe, awọn ara ilu ko ti i ni oye iṣẹ aṣofin daradara pe, bi eniyan ṣe n pẹ si ni idi iṣẹ aṣofin si ni wọn fi n wulo fun ilu si.

“Bi o ba ṣe pẹ nidii iṣẹ aṣofin ni wa a ṣe ni imọ ati iriri to. Amọ awọn eniyan maa n lero pe ibi ti eniyan kan le lọ ni saa kan tabi saa meji ko pada si ẹkun idibo rẹ ni. Eyi jẹ fifi owo ati iriri ṣofo, nitori pe wọn ti fun ẹ ni idanilẹkọọ to peye lẹnu iṣẹ naa, o si yẹ ki eleyii maa fara han ninu iṣesi ẹ, iru ofin ti ẹ n ṣe ati ilepa rẹ lẹnu iṣẹ naa.

“Lọdọ wa nibi wọn ri i gẹgẹ bi oyè to yẹ ki wọn maa to lati ọdọ ẹnikan si ikeji. A lọ si Ipinlẹ Illinois lorịlẹ-ede Amẹrika, wọn sọ fun wa pe, Oludari Ile Aṣofin Ipinlẹ naa ti lo saa kẹrinlelogun bayii, ti ki i si pe, ọdun kan ni wọn n lo fun saa kan.

“O ti di ogbontarigi lẹnu iṣẹ aṣofin. Bakan naa ni awọn orilẹ-ede to ti goke agba lagbaaye, ọpọ awọn aṣofin wọn lo ti lo bi ogun ọdun si ọgbọn ọdun ni awọn ile igbimọ aṣofin wọn, ti o ti jẹ ki wọn di akọṣẹmọṣẹ lẹnu iṣẹ wọn. Eleyii si maa n jẹ kori-o-ya fun awọn aṣofin yii lati tubọ fi gbogbo ara ṣiṣẹ fun orilẹ-ede wọn sii. Amọ lorilẹ-ede Naijiria, niwọn to ba ti lo saa kan tabi meji, agbara kaka ni wa a fi pada fun saa miiran, wọn a ti maa ṣaroye pe, ṣe iwọ nikan lo wa nibẹ?”

Akọṣẹmoṣẹ Amofin naa wa dupẹ lọwọ awọn eniyan agbegbe Agege ni Ipinlẹ Eko ti wọn tun dibo yan Oludari Ile Aṣofin naa, Aṣofin Mudashiru Ajayi Ọbasa pada wa lati wa ṣe aṣoju wọn. O ni ki i ṣe ohun to rọrun ki wọn maa fi ibo ran eniyan niṣẹ bẹẹ, eyi to jẹ pe wọn ni igbagbọ pupọ ninu onitọun, ati pe Aṣofin Ọbasa lo ni iriri ju ju ninu iṣẹ aṣofin ninu Ile Aṣofin Eko. O ni:

“Awa ti a ko ni lanfani lati pada si Ile Aṣofin Saa Kẹwaa yii, a ti wa, a ti sa ipa tiwa, orukọ wa ko si ni kuro ninu itan laelae. Mo gbadura ebutekọ ayọ fun awọn to maa ṣe Saa Kẹwaa Igbimọ Aṣofin yii.

“Mi o ni ṣaimọ Ile Aṣofin yii lara bi mo ba kuro. Sibẹ, gbagede gbogbo ara ilu Eko si ni Ile Aṣofin yii, maa si maa wa wo ijiroro ile lẹẹkọọkan, maa tun maa kopa ninu awọn ipade itagbangba lori awọn abadofin.”

Aṣofin Agunbiade ri anfani wiwa si Ile Aṣofin naa gẹgẹ iriri nla lati ba ọpọ awọn eniyan pataki ṣe ati lati wa ni awọn ipo pataki kan. Lara eyi lo ti ṣe Alaga fun Igbimọ Atunto Iṣẹ Aṣofin ni apa Iwọ-Oorun Gusu orilẹ-ede naijiria, ati anfani lati pade ọpọ awọn Olori Ọmọ ẹgbẹ Oṣelu to pọ ju ni awọn Ile Aṣofin kaakiri orilẹ-ede Naijiria, pẹlu ṣiṣe agbekalẹ iwe amulo itọsọna kan ṣoṣo fun awọn Ile Aṣofin ni apa Iwọ-Oorun Gusu yii.

Nigba ti awọn oniroyin n beere nipa ifẹ rẹ si awọn ẹkun rẹ ati idi to fi lero pe, wọn ko fi yan an pada, o dupẹ lọwọ awọn eniyan agbegbe rẹ fun iru anfani nla ti wọn fun un naa, ti o jẹ ẹni akọkọ aṣofin ti yoo pẹ bẹẹ ninu Ile Aṣofin bayii lati ẹkun naa. O ni:

“Ni ẹkun ọdọ mi, emi ni maa lo kọja saa meji ni Ile Aṣofin yii, ọpọ awọn eniyan ni wọn lo saa kan pere. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun asiko ti mo lo ninu Ile Aṣofin naa, sibẹ emi ni ẹni to si lo saa to pọ gẹgẹ bi oloṣelu kan ni Ile Aṣofin yii. Mo si dupẹ lọwọ awọn eniyan ni ẹkun idibo mi, fun akoko ti wọn fun mi lati fi sin wọn, eyi ti ko le kuro ninu itan, ọjọ kan naa ni yoo tan bi eyi. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe, mo wa sibi, mo kopa temi, mo si kuro nibi laaye ati lalaafia.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button