Wọn ti rọ awọn ọdọ lorilẹ-ede Naijiria lati maa fi ifẹ ati aanu han sira wọn ati awọn aladugboo wọn.
Eleyii ati awọn erongba miiran ni wọn fi ṣagbekalẹ Ajọ Alaanu Wuraade Adekọya, ti wọn ṣe iflọlẹ rẹ ni ọjọ Aje (Monday), ti wọn fi n ṣeranti akikanju Arabinrin Wuraade ti o fi ẹmi rẹ lelẹ ninu ijamba gaasi idana ti o lọ pa funra rẹ, pẹlu ero pe, bi oun ko ba ṣe ọkan akin bẹẹ, ọpọ ẹmi ni yoo mu lọ ni agbegbe naa.
Ajọ alaanu yii, ‘Wuraade Adekọya Foundation ni wọn gbe kalẹ lati fi saami ọjọ ibi rẹ to yẹ ko ṣe ni ọjọ kejila oṣu kẹfa ọdun 2023 ti yoo pe ọmọ ọdun mọkanlelogun.
Lara awọn eto ti wọn fi Ajọ Alaanu naa ṣe ni ṣiṣe abẹwo si Ile awọn Ọmọ Orukan, iyẹn ’Tripple Passion Home Initiative’ ni agbegbe Magodo ni Ipinlẹ Eko pẹlu awọn ẹbun ti wọn fun awọn ọmọ naa. Bakan naa ni wọn de ẹka itọju awọn alaisan ti wọn fara gba ijamba ina ni Ile Iwosan Gbogboogbo agbegbe Gbagada nibi ti Arabinrin Wuraade ti dakẹ lẹyin ijamba ina naa. Wọn si fun awọn alaisan naa ni nnkan. Bakan naa ni wọn tun na ọwọ ifẹ bayii si awọn ọmọde to-ku diẹ-kaato fun ni agbegbe Marọkọ ni Ipinlẹ Eko.
Ọpọ awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ ni Ile ẹkọ Fafiti Ijọba Apapọ ilu Eko (UNILAG) ṣapejuwe Oloogbe Wuraade gẹgẹ bi ọlọpọlọ pipe, ẹni ti ọrọ da lẹnu rẹ, ẹni ti ara rẹ ya mọọyan ati ẹni to nifẹ awọn ẹgbẹ rẹ.
Oluwapẹlumi Ogungbe, akẹkọọ ẹgbẹ rẹ ni ile-ẹkọ naa sọ pe, o jẹ ẹni to lọyaya gan-an. “Mo ranti igba ti mo wọ ile-iwe nigba yẹn, emi o tete mọ pe, ọmọ ṣọọṣi mi ni, oun lo sun mọ mi lo jẹ ki n mọ. O ba mi lọkan jẹ pe eleyii la fi n ṣe iranti rẹ, tori ọmọ kekere ni. Amọ o ye Ọlọrun. O jẹ ẹni ti o lawọ, eyi naa ni a fi n fi ajọ alaanu yii ṣe iranti rẹ, nitori ko gbọdọ ku bẹẹ.”
Arabinrin Adekọla Tofunmi, lara awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ sọ pe, “a wa nibi lonii nitori ifẹ ti a ni si i, eleyii ti o ko gbogbo wa papọ bayii. O jẹ ohun ibanujẹ pe, lọjọ ibi rẹ lonii, eleyii ni a wa n ṣe. O ṣeni laanu pe, iru eniyan bẹẹ ni nnkan bayii ṣẹlẹ si. Ki i ṣe tọrọ ẹnu, iku akin lo ku, nitori o ku nitori ki o le gba ẹmi awọn kan la ni.
“Bo ba ṣe pe ki i ṣe igboya akin to ni, ko yẹ ko ku iru iku bẹẹ. Amọ nitori ifẹ ti o ni si awọn eniyan gẹgẹ bi abuda adamọ Wuraade ti a mọ, o fi ẹmi rẹ lelẹ. Eleyii jẹ ẹdun ọkan ayeraye fun wa.”
Inu omije ẹkun ni ọpọlọpọ awọn ọrẹ Oloogbe Wuraade n sọrọ bayii. Bayii ni awọn ẹbi, ọrẹ ati awọn ẹgbẹ rẹ lati Fafiti Ijọba Apapọ ilu Eko, UNILAG ati awọn oṣiṣẹ lati Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko n ba awọn obi Oloogbe Wuraade kẹdun nibi eto yii.
Mama Oloogbe Wuraade, Arabinrin Bisọla Branco-Adekọya, ti o jẹ Oludari Ẹka Alukoro ati Iroyin Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko royin awọn iwa rere Wuraade nigba aye rẹ gẹgẹ bi ẹni to ni ifẹ, to gboya, ati olufọkanjin. Eleyii lo sọ nigba ti wọn n fi ajọ alaanu naa le lẹ.
Arabinrin Branco-Adekọya sọ pe eleyii wa lara ileri oun fun ọmọ oun lati maa ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi fun lọdọọdun, bo tilẹ jẹ pe ibanujẹ ni eyi pe, oun ṣe ti ọdun yii lẹyin rẹ:
“Wuraade jẹ akikanju obinrin, ti o ni ifẹ ati aanu lọpọlọpọ nigba aye rẹ. Ayẹyẹ ọjọ ibi lẹyin iku rẹ yii laṣeyọri nipasẹ akitiyan lati Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, awọn ẹbi ati awọn akẹgbẹ rẹ lati Ẹka Imọ Ibara-ẹni-sọrọ UNILAG. A fẹ ki iru ifẹ yii tẹ siwaju ni ọpọ ọdun si asiko yii lati fi maa ṣe iranti Wuraade.
“O gbe igbe aye daradara nitori o nipa rere laye awọn eniyan, eyi ti mo le fi gbogbo ẹnu sọ, botilẹ ṣe pe o ti ku bayii. Oun naa ti dara pọ mọ awọn ajọ alaanu bayii nigba aye rẹ ti wọn fi n ṣaanu. A bẹrẹ ọkan fun un paapaa ti a n ba a fi awọn oogun to ba wọn pupọ sita fun awọn ti o le ṣe iranlọwọ.”
Bakan naa ni o mẹnu ba pataki ajọ alaanu yii, lati fi ṣe iranlọwọ fun awọn eniyan ni iye ti agbara ka, gẹgẹ bi Wuraade ṣe n ṣe nigba aye rẹ.
Baba Oloogbe Wuraade naa, Ọgbẹni Michael Adekọya ninu ọrọ rẹ sọ pe, pẹlu bi ọpọ awọn eniyan ṣe wa sibi eto yii, o fi han pe, wọn mọ riri ọmọ rẹ naa. O wa rọ awọn ọmọde lati ni iwa rere ifẹ ati aanu si ọmọlakeji wọn.
Ayẹyẹ naa ni awọn akopa ti wọ aṣọ alawọ funfun ti wọn kọ ‘Wuraade Adekoya Foundation’ gbagada si lara, pẹlu fọto nla rẹ ti wọn n gbe soke, ti wọn n ṣafihan.
Leave a Reply