Awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti dibo yan Aṣofin Mudashiru Ajayi Ọbasa gẹgẹ bi Oludari wọn fun fun igba kẹta.
Ni ọdun 2015 ni wọn kọkọ yan an, wọn tun yàn ni ọdun 2019, ki wọn to tun pada yan an bayii ni ọdun 2023.
Bakan naa ni wọn yan Aṣofin Lasbat Meranda g̣ẹgẹ bi Igbakeji Oludari Ile Aṣofin naa. Igbakeji Olori Ọmọ Ẹgbẹ Oṣelu to pọju tẹlẹ, Aṣofin Noheem Adams ni wọn fi jẹ Olori Ọmọ Ẹgbẹ Oṣelu to pọju ninu Ile Aṣofin naa bayii. Aṣofin Adedamọla Kasumu ni wọn fi jẹ Igbakeji Olori Ọmọ Ẹgbẹ Oṣelu to pọju. Aṣofin Mojeed Fatai ni wọn fi jẹ Ọlọpaa Ile, nigba ti Aṣofin David Setonji di Igbakeji Ọlọpaa Ile Aṣofin naa.
Wọn yan awọn alaṣẹ naa nigba ti Gomina Babajide Sanwo-Olu ti Ipinlẹ Eko ṣi Ile Aṣofin saa kẹwaa naa, ẹni ti o wa ninu gbọngan Ile Aṣofin naa pẹlu Igbakeji rẹ, Ọmọwe Ọbafẹmi Hamzat ati awọn ẹmẹwa wọn.
Ninu lẹta ti Gomina fi ṣọwọ si Ile Aṣofin naa, eyi ti Akọwe-agba Ile Aṣofin yii, Ạmofin Ọlalekan Ọnafẹkọ kà ni Gomina Sanwo-Olu ti fi mulẹ pe igbese ṣisị Ile Aṣofin tuntun yii wa ni ibamu pẹlu ipele karunlelọgọrun-un abala kẹta (section 105 (3) ofin orilẹ-ede Naijiria.
Gomina Sanwo-Olu tun wa ni ijokoo nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin naa yan awọn olori wọn.
Aṣofin Mudashiru Ọbasa ni aṣofin ti saa rẹ pẹ julọ ninu Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, ẹni ti Aṣofin Temitọpẹ Adewale yan gẹgẹ bi aba lati di Oludari Ile Aṣofin naa fun igba kẹta, eyi ti Aṣofin Sylvester Ogunkelu kín aba naa lẹyin. Lẹyin eyi ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ fi ibo gbe si aba naa lẹyin. Aṣofin Ọbasa ni yoo maa dari Saa kẹwaa Ile Aṣofin naa.
Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Oludari naa dupẹ lọwọ awọn akẹgbẹ rẹ gbogbo ti wọn ṣatilẹyin fun un lati pada si ipo Oludari naa gẹgẹ bi igbẹkẹle wọn ninu rẹ. O tun dupẹ lọwọ awọn aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, paapaa olori wọn ti o ti di Aarẹ orilẹ-ede yii bayii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ati awọn agbaagba ẹgbẹ paapaa Igbimọ GAC ni Ipinlẹ Eko. Bakan naa lo dupẹ lọwọ Gomina Babajide Sanwo-Olu, Igbakeji rẹ, Ọmọwe Ọbafẹmi Hamzat ati awọn ẹmẹwa wọn gbogbo fun iṣẹ ilu ati atilẹyin wọn fun Ile Aṣofin naa. Bakan naa lo ki awọn lọbalọba loyeloye to wa ni ikalẹ, pẹlu awọn eniyan gbogbo ti wọn wa nibẹ.
O wa rọ awọn akẹgbẹ rẹ ninu Ile Aṣofin naa lati ṣiṣẹ takuntakun fun aṣeyọri ilepa ati erongba Ile Aṣofin naa. Bakan naa ni o pe fun ifọwọsowọpọ awọn ẹka ijọba to ku fun aṣeyọri erongba idagbasoke Ipinlẹ Eko. O ni:
“Pẹlu ifọwọsowọpo, a ni anfani mimu igba ọtun ba Ipinlẹ Eko ti gbogbo awọn ara ilu yoo le jẹ anfani to pọ, Ipinlẹ Eko ti yoo jẹ ibi ti aabo to nipọn bi awọ erin yoo wa, Ipinlẹ Eko ti yoo jẹ ibi awokọṣe idagbasoke alailẹgbẹ fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ati lagbaaye.”
Gbogbo awọn ọmọ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko jẹ ogoji. Ni bayii, awọn ti wọn dibo yan pada lati saa to kọja jẹ mọkandinlogun nigba ti awọn tuntun jẹ mọkanlelogun.
Awọn mejidinlogoji ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nigba ti meji jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣlu Labour Party (LP).
Leave a Reply