Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó fọwọ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àbádòfin àti Ìpinnu nínú sáà kẹsàn-án Ilé Aṣòfin náà- Aṣòfin Ọbasá

0 226

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa sọ ọ di mimọ ní Gbọgan Ile Aṣofin naa pe, awọn ti sọ abadofin mẹrindinlaadọta (46) di ofin, nigba ti awọn ti fọwọ si ipinnu to le ni ọgọfa (120) ati igbekalẹ awọn ilana iṣiṣẹ kan laarin ọdun mẹrin saa kẹsan-an ti wọn lo tan yii. O ni eleyii ti mu aṣeyọri nnlanla ba idagbasoke Ipinlẹ Eko.

Aṣofin Ọbasa sọrọ yii nibi ipade ikẹyin Ile Aṣofin naa fun saa kẹsan-an to waye lọjọ Ẹti (Friday) ni Gbongan Ile Igbimọ Aṣofin naa ni Ikẹja. O ni ojuṣe Ile Aṣofin naa lati ṣe awọn ohun ti awọn ṣe naa, gẹgẹ bi igbẹkẹle ati ifẹ ti awọn ara ilu ni ninu awọn. O sọ pe:

Ẹyin Aṣofin akẹgbẹ mi, pẹlu igboya ni mo fi sọ pe, a ti ṣe gudugudu meje lati mu igberu ba igbe-aye awọn olugbe Ipinlẹ Eko nipa awọn abadofin to n ṣe irọrun fun awọn ara ilu ti a ti sọ di ofin. Mo layọ lati sọ fun yin pe, lati osu kẹfa ọdun 2019 titi di asiko yii, Ile Aṣofin yii ti sọ abafofin mẹrindinlaadọta di ofin, ti wọn si ti fọwọ si ipinnu to le ni ọgọfa pẹlu agbekalẹ awọn ilana iṣiṣẹ kan.”

“Awọn abadofin ti a sọ yii ti mu igberu ba iṣẹ aṣofin, pẹlu idagbasoke si Ipinlẹ Eko lapapọ. Bo ti le ṣe pe, asiko ko si lati maa sọ awọn abadofin yii lẹyọ kọọkan, sibẹ mo dupẹ pe aṣeyọri alailẹgbẹ  la ṣe lati fi ẹsẹ ijọba rere mulẹ ni Ipinlẹ Eko pẹlu ilana aṣofin to dara, bo tilẹ ṣe pe, arun COVID-19 fẹ ṣe idiwọ ni asiko naa.”

Aṣofin Ọbasa ṣalaye pe lara aṣeyọri iṣakoso ohun ni lati ṣe agbekalẹ ile-ẹkọ fun ojuṣe ati iṣẹ iwadii aṣofin, eleyii ti wọn lanfani lati gba abadofin rẹ wọle ni ọdun 2022, ti wọn pe ni “Law for The Establishment of The Institute for Legislative Studies and Research”, eleyii ti yoo fun awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin naa lanfani lati le ni imọ kikun nipa ojuṣe wọn gbogbo.

Oludari Ile Aṣofin naa dupẹ pupọ lọwọ awọn akẹgbẹ rẹ ninu Ile Aṣofin naa ti wọn jọ fọwọ sowọpọ ṣiṣẹ naa fun aise oju ṣaaju, ifẹ wọn fun iṣẹ naa, ifarajin wọn lati fi sin awọn ara ilu ni Ipinlẹ Eko.

O tun dupẹ lọwọ Akọwe-agba Ile Aṣofin naa, Amofin Ọlalekan Ọnafẹkọ, fun atilẹyin rẹ ati awọn oṣiṣẹ to ku, awọn oṣiṣẹ amugbalẹgbẹ rẹ ati ti awọn Aṣofin yooku. O ni: “Mo dupẹ o! Iṣẹ takuntakun ati ẹmi ifarajin yin lo kopa ribiribi fun aṣeyọri awọn erongba ati ilepa wa yii.”     

Oludari Ile Aṣofin naa tẹ siwaju; “mo tun dupẹ lọwọ awọn Olori ẹgbẹ oṣelu wa, paapaa Aṣiwaju Ẹgbẹ Oṣelu All Progressives Congress (APC), ti o ti di Aarẹ orilẹ-ede Naijiria bayii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, GCFR fun atilẹyin alailẹgbẹ wọn fun aṣeyọri Saa kẹsan-an Ile Igbimọ Aṣofin yii.”

O wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ Aṣofin tuntun ti wọn dibo yan fun saa kẹwaa lati gbiyanju kọ ẹkọ lati ara awọn ti wọn ba nibẹ ati pe awọn yoo ṣe iranlọwọ to yẹ fun wọn. O ni; “fun ẹyin ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin yii ti o n pada, ẹ jẹ ki awọn to ṣẹṣẹ de jẹ anfani awọn iriri ati ọgbọn wa lẹnu iṣẹ yii, eleyii yo tun le mu alekun ba aṣeyọri ti a ti ni tẹlẹ.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button