Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó fọwọ́ sí ìṣúná-owó 2023 Ìpínlẹ̀ Èkó

0 322

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko labẹ Oludari Ile, Aṣofin Mudashiru Ọbasa sọ abadofin iṣuna owo Ipinlẹ Eko fun ọdun 2023 di ofin.

Abadofin iṣuna owo oni Tirilioonu kan ati Bilionu bii ẹgbẹrin naira (N1,768,014,155,285) ni wọn gba wọle lọjọ Aje, nigba ti Oludari Ile gboriyin fun akitiyan awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin naa fun iṣẹ takuntakun wọn lori eto iṣuna-owo naa.

Atupalẹ iṣuna-owo naa fi han pe, Bilionu lọna meji-din-laadọta le-ẹẹdẹgbẹrin ati milionu diẹ owo naira (N748,096,508,571) jẹ Inawo Onigbadegba (Recurrent Expenditure), nigba ti Tiriliọnu kan le Biliọnu diẹ naira (N1,019,917,646,713) jẹ Inawo Iṣẹ Akanṣe Ilu (Capital Expenditure) fun ibẹrẹ ọdun titi de ipari ọdun 2023.

Apapọ nnkan bi miliọnu mẹta le ẹgbẹrin naira (N802,987,206) ni wọn fọwọ si fun Ile-iṣẹ Ijọba to n moju to Eto Ọrọ-aje ati Iṣuna owo Ilu fun Inawo Iṣẹ Akanṣe Ilu, nigba ti wọn fọwọ si Biliọnu kan ati igba miliọnu naira (N1,200,000,000) fun Eto iṣẹ iranlọwọ ati aanu fun awọn ara ilu ninu Ile-iṣẹ Ijọba yii .

Aṣofin Ọbasa sọ pe ọwọ ọkunkundun ti awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin naa fi mu iṣẹ eto iṣuna-owo ilu naa fi han pe wọn nifẹẹ Ipinlẹ Eko, ati pe awọn olugbe ipinlẹ yii yoo si gbadun ijọba yii siwaju, paapaa bi wọn ba dibo fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ninu eto idibo to n bọ.

Ninu oṣu kẹwaa ọdun yii ni Gomina Babajide Sanwo-Olu ti Ipinlẹ Eko ṣe agbekalẹ abadofin eto iṣuna-owo ọdun 2023 yii siwaju Ile Aṣofin yii, nibi ti Aṣofin Ọbasa ti woye pe, gbogbo ohun to ba wa ninu abadofin naa gbọdọ jẹ eyi ti yoo ṣe adinku iṣẹ ati oṣi, ti yoo si mu irọrun ba awọn olugbe ipinlẹ yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button