Take a fresh look at your lifestyle.

Olùdarí Ilé Aṣòfin Eko rọ àwọn Aṣofin láti fọwọ́ ọ̀kúnkúndùn mú àyẹ̀wò ìṣúná owó ọdun 2023 ìpínlẹ̀ náà

0 299

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti rọ awọn igbimọ ile Aṣofin naa lati ṣiṣẹ finnifinni lori eto iṣuna owo Ipinlẹ Eko ti ọdun 2023 ti wọn gbe wa siwaju wọn lati ri i daju pe iṣiro owo inu eto iṣuna owo naa wa ni ibamu pẹlu owo to n wọle sapo ijọba.

Aṣofin Ọbasa sọrọ yii nibi ipade apero ọlọjọ mẹta lori eto iṣuna owo naa ti wọn pe akọle rẹ ni “Ṣiṣe atilẹyin fun eso rere ijọba Ipinlẹ Eko ni lọwọlọwọ yii”, eleyii ti wọn ṣagbekalẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ ati awọn ọṣiṣẹ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko.

Nigba ti o n gboriyin fun awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin yii, Aṣofin Ọbasa gba awọn igbimọ yii ni iyanju lati maa fi kun imọ wọn, ki wọn le maa beere awọn ibeere to tọ lọwọ awọn ile-iṣẹ ijọba, awọn ẹka ile-iṣẹ ijọba ati awọn ajọ ile-iṣẹ ijọba gbogbo lori ọrọ eto iṣuna owo wọn, ati lẹnu iṣe iṣayẹwo awọn iṣẹ wọn naa. O ni:

“Ni gbogbo agbaye ni ọrọ-aje ti n dẹnu kọlẹ bayii, eleyii ti o n ṣakoba fun iṣuna owo ilu lọna kan tabi omiran. Bẹẹ naa lo ṣe jẹ ni ti Ipinlẹ Eko naa. Fun idi eyi, bi iṣuna owo ilu maa ṣe wa ni ibamu pẹlu owo to n wọle sapo ijọba ni o yẹ ki Ile Aṣofin yii foju sunukun wo. Bi ẹka amuṣẹṣẹ ijọba ba ti gbe iṣẹ akanṣe kan wa, ki a wo owo ati iwulo rẹ ni finnifinni”.

Ninu ọrọ ikini-kaabọ rẹ, Akọwe-agba Ile Aṣofin naa, Amofin Ọlalekan Ọnafẹkọ fi mulẹ pe anfani ni eyi jẹ ti Ile Igbimọ Aṣofin yii yoo fi le ṣayẹwo ohun to wa ninu eto iṣuna owo ilu ọdun 2023 fun Ipinlẹ Eko, ki aṣeyọri le ba amulo iṣuna owo yii fun awọn eniyan ipinlẹ yii lati ọwọ awọn aṣofin yii.

Ile-iṣẹ adanilẹkọọ ‘Hybitel Consultant’ ti o fọwọ sowọ pọ pẹlu Ile Aṣofin yii lati ṣagbekalẹ idanilẹkọọ yii ni Akọwe-agba Ile naa sọ pe yoo ṣe iranlọwọ fun awọn aṣofin yii lati nimọ daradara nipa itupalẹ iṣuna owo onitiriliọnu kan le bii biliọnu ẹẹdẹgbẹrin naira (N1.692 Trillion) ti Gomina Babajide Sanwo-Olu gbe wa siwaju Ile Aṣofin naa.

O woye pe ipade apero naa yoo tun jẹ ki awọn aṣofin naa foju inu wo bi ijọba ṣe ṣamulo iṣuna owo ọdun 2022, ki wọn si mọ awọn ohun to yẹ ni pataki lati mu wọ iṣuna owo ọdun 2023 yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button