Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Sanwó-Olú ṣe àgbékalẹ̀ Àbádòfin Ìṣúná–owó 2023 síwájú Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó

0 448

Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa tẹwọ gba abadofin eto iṣuna owo ‘onitiriliọnu kan le ni biliọnu mẹjọ-din-lẹẹdẹgbẹrin ati ẹgbẹta miliọnu-le-mọkanle-laadọrin naira’ (N1,692,671) ti ọdun 2023 lati ọwọ Gomina Babajide Sanwo-olu ti Ipinlẹ Eko. Eleyii ti Oludari Ile naa sọ pe yoo moju to awọn opo mẹta pataki kan fun anfani awọn olugbe ipinlẹ yii.

Abadofin iṣuna owo naa ti wọn pe akori rẹ ni, “Eto Iṣuna-owo Ifojusun fun Itẹsiwaju Idagbasoke Ilu” ni  eto iṣiro inawo iṣẹ akanṣe ilu (Capital) rẹ jẹ iko marundinlọgọta ninu ida ọgọrun-un, nigba ti iṣiro inawo atigbadegba (Recurrent) jẹ iko marundinlaadọta ninu ida ọgọrun-n. Gomina Sanwo-Olu ṣalaye pe, ”Eto iṣuna owo fun itẹsiwaju idagbasoke ilu yii la o fi gbe Ipinlẹ Eko de ipele to kan.”

Aṣofin Ọbasa tẹ siwaju ninu ọrọ rẹ pe, nnkan o rọgbọ fun awọn eniyan lasiko yii, ati pe o yẹ ki eto iṣuna owo ọdun 2023 yii le koju ọpọ awọn ipenija bayii. O ni: “O yẹ ki eto iṣuna ọdun 2023 yii le ṣadinku awọn ipenija ọrọ-aje bayii, lati le moju to adinku iṣẹ ati mimu igberu ba igbesi aye-irọrun awọn ara ilu gẹgẹ bi ara erongba ti agekuru rẹ jẹ THEME to jẹ koko iṣejọba ipinlẹ yii.”

Oludari Ile Aṣofin naa sọ pe, botilẹ jẹ pe, ijọba Ipinlẹ Eko ti n sa gbogbo ipa lati mu idagbasoke ba ipinlẹ yii, sibe awọn ara ilu si nilo anfani ijọba tiwa-n-tiwa siwaju. Bẹẹ lo tun rọ ijọba apapọ lati fọwọ si aba yíya owo kan pataki silẹ fun Ipinlẹ Eko latari bi ero ṣe pọ lapọju ni ipinlẹ yii.

O wa ṣe ileri pe Ile Aṣofin naa yoo sa gbogbo ipa lati ṣayẹwo abadofin iṣuna owo naa ni finnifinni ki wọn to ṣe amulo rẹ fun anfani awọn ara ilu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button