Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó pè fún ìgbé-ayé ìrọ̀rùn àwọn olùkọ́

0 245

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko labẹ Oludari wọn, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti gboriyin fun iṣẹ akin awọn olukọ lati mu igbesi aye rọrun lawujọ, pe wọn tọ si ere wọn nile aye.

Ile Aṣofin naa fọrọ akin yii mule ninu ijiroro wọn lẹyin ti Aṣofin Ọkanlawọn Sanni, ti o jẹ Alaga fun Igbimọ to n mojuto Eto Ẹkọ ninu Ile Aṣofin naa mu ọrọ naa wa gẹgẹ bi aba, nigba ti o tẹnu mọ ọn pe awọn olukọ ti ko ipa ribribi tun aṣeyọri ẹnikọọkan lawujo, o si tọ ki awujọ lati mọ riri wọn.

Aṣofin Abiọdun Tobun pè fun alekun owo ajẹmọnu fun awọn olukọ ni awọn ile-ẹkọ Alakọọbẹrẹ ati Girama ki o le jẹ ohun iwuri fun awọn eniyan lati le ṣe iṣẹ yii.

Aṣofin Bisi Yusuff rọ ijọba lati tubọ gba olukọ si ile-iwe si i, nitori awọn olukọ to n kọ ọpọ awọn akẹkọọ ni ile-iwe ko to nnkan.

Aṣofin Kẹhinde Joseph rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ ati ẹgbẹ awọn olukọni fafiti orilẹ-ede yii, ASUU lati yanju aawọ aarin wọn ki wọn le pada sẹnu iṣẹ.

Aṣofin Ibrahim Layọde sọ pe o yẹ ki wọn ṣe atunṣe si awọn ile-iwe to wa ni igberiko ipinlẹ yii lati yá awọn olukọ ti wọn ba gbe lọ sibẹ lara lati le ṣiṣẹ nibẹ.

Bayii ni awọn aṣofin naa mu imọran wa loriṣiiriṣi lati le tubọ mu igberu ba igbe-aye irọrun awọn olukọ.

Ninu ọrọ rẹ, Oludari ile naa, Aṣofin Ọbasa sọ pe ọna kan ṣoṣo ti awọn olukọ le fi ri ere wọn jẹ nile aye ni ki wọn ṣe wọn daradara lẹnu iṣẹ ati lẹyin ti wọn ba fẹyin ti lẹnu iṣẹ.

O wa rọ ijọba lati ri i daju pe wọn pese awọn ohun amayerọrun si awọn ile-ẹkọ, ti yoo fi rorun fan awọn akẹkọọ lati kẹkọọ, ati fun awọn olukọ lati le kọ awọn ọmọ.

Aṣofin Ọbasa tun rọ Ile-iṣẹ Ijọba fun Eto Ẹkọ ni Ipinlẹ Eko lati mojuto awọn ile-ẹkọ aladani ti wọn n da silẹ bayii ti ko boju mu, ki wọn si moju to bi ina ẹkọ ṣe n jo ajorẹyin.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button