Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó fọwọ́ sí àbádòfin tó rọ̀ mọ́ dídáàbò bò àwọn ẹlẹ́rìí àti àwọn tó fara gbá nínú ìjàmbá
Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti fọwọ si abadofin to daabo bo awọn ẹlẹrii ati awọn to fara gba ninu ijamba kan ni Ipinlẹ Eko.
Ofin naa ti wọn pe akori rẹ ni, “Abadofin fun Ofin ti yoo pese Ẹtọ fun awọn to ba fara gba ninu Ijamba kan ati awọn Eḷẹrii kan, pẹlu awọn nnkan miiran to jẹ mọ eyi” ni wọn sọ di ofin ninu ijiroro ile naa lọjọBọ (Thursday) eyi ti Oludari Ile naa Aṣofin Mudashiru Ọbasa dari.
Ofin naa faaye sile lati pese iranlọwọ to yẹ lati daabo bo awọn to fara gba ninu ijamba kan ati awọn ẹlẹrii kan ti wọn ni awọn iroyin ẹlẹgẹ kan lọwọ, paapaa lati fi okodoro ẹsun kan mulẹ, ti wọn wa n koju awọn ipenija kan lọwọ awọn ẹṣọ alaabo tabi lẹnu igbẹjọ naa.
Lara ofin naa fi mulẹ pe,“Olukuluku ati awọn ẹṣọ alaabo lo gbọdọ ri i gẹgẹ bi ojuṣe labẹ ofin lati ṣe iranlọwọ lati gbe ẹni to ba kagbako ijamba ọkọ tabi ikọlu miiran lọ si ile-iwosan to ba sun mọ wọn fun itọsun loju ẹsẹ.
Bakan naa ni o tun ka pe, “Ile-iwosan Ijọba tabi aladani gbọdọ pese itọju loju ẹsẹ fun ẹnikẹni to ba fara pa latara ijamba kan tabi ti o fara gbọgbẹ ibọn ati awọn ifarapa to pọ miiran.”
O fi mulẹ pe eyikeyii ile-iwosan to ba kuna lati tẹle awọn ikilọ inu ofin yii yoo foju wina ijiya.
O ni, “Bi ile-iwosan aladani kan ba gba alaisan kan to kagbako ijamba, lati ṣe itọju rẹ ni lati tete fi to ajọ yii leti laarin ọjọ meji, ki wọn le da owo itọju wọn pada paapaa bi awọn mọlẹbi alaisan naa ko ba lagbara lati san owo naa.”
Nigba ti wọn ka abadofin naa lẹẹkẹta ninu ijiroro naa, ti Ile si fọwọ si i, Oludari Ile Igbimọ Aṣofin naa paṣẹ fun Akọwe-agba Ile, Amofin Ọlalekan Ọnafẹkọ lati fi ẹda abadofin naa ṣọwọ si Gomina Babajide Sanwo-Olu lafi fọwọ si i ki o le di ofin amulo.
Leave a Reply