Apapọ Igbimọ to n moju to Apo Owo Ijọba Ibilẹ ati Igbimọ to n moju to Iṣakoso Ijọba Ibilẹ ati Agbegbe rẹ ninu Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko labẹ Oludari wọn, Aṣofin Mudashiru Ọbasa, bẹrẹ ṣiṣe ayẹwo iṣẹ awọn ogun Ijọba Ibilẹ ati Agbegbe Idagbasoke Ijọba Ibilẹ mẹtadin-logoji to wa ni Ipinlẹ Eko. Eyi ti wọn yoo ṣe titi Ọjọbọ, ọjọ kọkanla oṣu kẹjọ ọdun yii.
Wọn bẹrẹ iṣẹ agbeyẹwo naa ni Agbegbe Ijọba Ibilẹ Koṣọfẹ, Agboyi-Ketu, Ikosi-Isheri, Yaba, Lekki, Ibeju Lekki, Imọta, Ẹpẹ, Isọlọ, Lagos Island, Itirẹ-Ikate ati awọn miiran.
Erongba ojuṣe yii ni lati ri i daju pe awọn Ijoba Ibilẹ ati Agbegbe Idagbasoke Ijoba Ibilẹ yii na awọn owo ti wọn ya fun wọn ninu iṣuna owo ọlọdọọdun lọna to tọ, gẹgẹ bi Ile Igbimọ Aṣofin yii ṣe fọwọ si i, paapaa fun idagbasoke ilu.
Lẹyin ojuṣe iṣagbeyẹwo iṣẹ awọn ijọba ibilẹ yii, Apapọ Igbimọ Ile naa yoo fi abajade wọn ṣọwọ sile ninu ijiroro wọn, nibi ti wọn yoo ti foju sunnukun wo o.
Lara awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Igbimọ Aṣofin yii to wa ninu Apapọ Igbimọ yii ni Aṣofin Mojeed Fatai (Alaga, Igbimọ to n moju to Apo Owo Ijọba Ibilẹ), Aṣofin Olawale AdulSobur, (Alaga, Igbimọ to n moju to Iṣakoso Ijọba Ibilẹ ati Agbegbe rẹ), Aṣofin Rotimi Olowo, Aṣofin Hakeem Ṣokunle, Aṣofin Nurudeen Saka-Solaja, Aṣofin Rauf Age Suleiman, Aṣofin Kẹhinde Joseph, Aṣofin Victor Akande, Aṣofin Mosunmọla Ṣangodara ati Aṣofin Fatai Oluwa.
Leave a Reply