Take a fresh look at your lifestyle.

Ile Aṣofin Eko fọwọ si Abadofin agbekalẹ Ile ẹkọ Idanilẹkọọ fun Awọn ẹṣọ Alaabo

0 467

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti fọwọ si Abadofin ti ẹọṣ yoo ṣe agbekalẹ Ile ẹkọ Idanilẹkọọ fun Awọn ẹṣọ Alaabo. Eleyii ni wọn fọwọ si lẹyin ti wọn ka a ni igba kẹta ninu gbọgan ile lọjọ Aje, Monday.
Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti o ṣaaju ijiroro naa paṣẹ fun Adele Akọwe-agba Ile naa, Ọgbeni Ọlalekan Ọnafekọ lati fi ẹda ofin naa ṣọwọ si Gomina Babajide Sanwo-Olu lati buwọ lu u ki o le di ofin amulo ilu.
Lẹyin ipade ijiroro Ile naa, Aṣofin Sanai Agunbiade, Olori ọmọ ẹgbẹ Oṣelu to pọ julọ ninu Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko sọ pe ofin naa yoo le fẹsẹ iṣẹ awọn ẹṣọ alaabo ni Ipinẹ Eko mulẹ lati le mu igberu ba iṣẹ wọn paapaa lati le koju awọn ipenija to n jẹyọyo lẹnu iṣẹ wọn bayii.
Ninu ọrọ rẹ, Aṣofin Victor Akande ti o jẹ Alaga Igbimọ to n moju to Eto Idajọ, ẹtọ ọmọ-Eniyan, Ifẹhonuhan ara-ilu, ati Eto Oṣelu ni Ipinlẹ Eko fi kun ọrọ naa pe ni ọpọ igba ni awọn ara ilu maa n fẹsun kan pe awọn agbofinro ko ni ẹkọ kikun lati ṣiṣẹ wọn. Eyi lo mu ki ẹka amuṣẹṣe ati ẹka aṣofin ijọba fi pinnu lati foju inu wo kudiẹkudiẹ to yẹ ka ṣiṣẹ le lori, ki a le ni ikọ agbofinro to koju osuwon. O ni:
“Ofin yii yoo seranwọ lati jẹ ki awọn ẹṣọ alaabo yii koju osuwon lẹnu iṣẹ wọn.”
O ni nipele nipele ni eto idanilekọọ yii yoo, eyi ti tawọn eso oju ona LASTMA yoo yatọ si ti ẹṣọ KAI ati awọn miiran bẹẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button