Take a fresh look at your lifestyle.

Tinubu ṣe gudugudu meje fun idagbasoke Eko- Ọbasa

Bi Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ṣe n ṣajọyọ Tinubu lẹni aadọrin ọdun

0 317

Awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti ṣapejuwe Olori Ẹgbẹ Oṣelu All Progressives Congress (APC), ti o jẹ Gomina tẹlẹ ni Ipinlẹ Eko, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu gẹgẹ bi akikanju eniyan, ẹni ti o ṣe iranlọwọ nla fun Ile Igbimọ Aṣofin naa lati ni ominira si iṣuna –owo wọn.
Awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Igbimọ Aṣofin naa gboriyin lọlọkan-o-jọkan fun ogbontarigi oloṣelu naa ninu ipade ijiroro pataki ti wọn fi sọri rẹ lati fi yẹ ẹ si fun ayẹyẹ aadọrin ọdun to pe ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2022 yii.
Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ṣapejuwe Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu gẹgẹ bi alaanu, ti o ti saseyori gẹgẹ bi olori. O ni:
“Eleyii je anfani lati mo riri Asiwaju Bọla Ahmed Tinubu gege bi akikanju asiwaju. Nigba ti o n koju ilakaka lati odo awon egbe oselu alatako, o duro digbidigbi lati koju Ijoba Apapo. O to lati sajoyo fun iru awon eniyan bayii ti won ti kopa riribi fun idagbasoke ilu. Gbogbo eyi ni Ile Igbimọ Aṣofin yii fi fakoyo.”
“Ile Igbimọ Aṣofin yii lanfani eto isuna-owo won funra won nitori iranlowo Asiwaju ni. Nigba to wole gege bi Gomina Ipinle yii ni owo to n wole sapo ijoba labele gberu sii.”
Ninu oro tire, Igbakeji Oludari Ile naa, Aṣofin Wasiu Eshinlokun-Sanni tenu mo on pe Tinubu ti se gudugudu meje yaaya mefa lati fese oselu tiwa-n-tiwa mule. O ni:
“O rorun fun un lati lati darapo mo egbe oselu People’s Democratic Party (PDP), a mo ko se be, o duro ti egbe oselu onitesiwaju. A ro o ko te siwaju ninu akitiyan re lati gba ipo Aare orile-ede yii bayii.
Aṣofin Victor Akande lo anfani naa lati benu ate lu awon to n tako Aṣiwaju Bọla Tinubu paapaa fun erongba re lati di Aare orile-ede yii, pe oju won ni yoo se bi o ba di Aare naa. Bakan naa ni o sapejuwe Tinubu gege bi “ogbontarigi oloselu, ti isiro oselu ye perepere, ti o jẹ agba asiwaju orile-ede Naijiria tuntun.”
Aṣofin Abiọdun Tọbun so pe Asiwaju Tinubu je eni owo pataki paapaa fun iwa mimu ileri se re, ati eni ti o ni ife orile-ede yii ni ookan aya re.. O wa fi kun un ki a satileyin fun lati de ipo Aare ti o fe de ni odun 2022.
Olori Omo egbe Oselu to po ju ninu Ile Igbimo Aṣofin naa, Aṣofin Sanai Agunbiade sagbejuwe Asiwaju Bola Tinubu gege bi eni ti ki i se eleyemeya, o je olori to fa gbogbo ẹya mọra, o si je oloselu ti tie yato.
Aṣofin Rotimi Abiru so pe “Tinubu je enikan ti o ni gbongbo kaakiri, olori tooto. Eni ti je ‘Mungo Park akoko wa. Ipile Eko tuntun bayii je ise owo re, bii idasile awon ajo amusese LASTMA, LAWMA, OPD ati awon miiran.”
Aṣofin Gbọlahan Yishawu sapeju Tinubu gẹgẹ bi eni to ni emi iforiji, to si fa opo eniyan mora. O gbadura pe Olorun fun un ni emi gigun sii. Amin.
Bayii ni gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ Ile Igbimọ Aṣofin Ipinle Eko se n yobo Asiwaju Tinubu gege bi eni ti opo eniyan ti ara re di olori ni ipo nlanla lorile-ede yii bayii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button