Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti fọwọ si Iṣuna owo oniTiriliọnu kan ati Miliọnu lọna mejidinlọgọta-le-ni-ẹẹdẹgbẹrin naira (N1.758Tr) gẹgẹ bi Iṣuna owo ọdun 2022 fun Ipinlẹ Eko.
Abadofin eto iṣuna owo onitirilionu kan ati milionu lọna mejidinlogoji (N1.38Tr)ti Gomina kọkọ gbe wa siwaju Ile naa ni wọn ṣatunṣe diẹ si, ti o di Tiriliọnu kan ati Biliọnu lọna mejidinlọgọta-le-ni- ẹẹdẹgbẹrin naira (N1.758Tr) yii.
Abadofin iṣuna owo naa ni wọn sọ di ofin lOjoRu, Wednesday ninu ijokoo ile, labe Oludari Ile Igbimọ Aṣofin naa, Aṣofin Mudashiru Ọbasa, lẹyin ti Alaga Igbimọ to n moju to Eto ọrọ-aje ati eto Iṣuna-Owo ilu onigbadegba, Aṣofin Gbọlahan Yishawu ṣagbekale abajade igbimọ naa lori abadofin eto iṣuna owo yii.
Ninu alaye Alaga naa, isuna owo naa ni won ṣe alekun owo to ku ninu isuna owo odun 2021 si, eleyii ti wọn fi kun ara owo iṣẹ akanṣe ẹlẹkunjẹkun. Iṣuna owo iṣẹ akanṣe jẹ iko mẹrin-din-laadọrin, nigba ti inawo onigbadegba jẹ iko mẹrin-le-lọgbọn ninu ida ọgọrun-un (66:34).
Nigba ti inawo onigbadegba je Biliọnu lọna ẹgbẹta din mẹsan-an, miliọnu lọna ọrin-le-nigba, ẹgbẹrun mẹta-le-lẹgbẹrin ati mẹrin-din-laadọrun-le-ni- ẹgbẹta owo naira (N591,280,803,486 BN), ti iṣ ẹ akanṣe jẹ Tirilionu kan, Biliọnu lọna mẹrin-din-lọgọsan-an Miliọnu lọna mẹẹdogun-le- ẹẹdẹgbẹrun, ẹgbẹrun lọna mẹta-le-logoji-le-ni- ẹgbẹrin ati meji-din-lọgọta-le-ni-ọọdunrun owo naira (N1.166,915 843,358). Eleyii je ki iṣiro iṣuna owo ọlọdọọdun 2022 naa jẹ nnkan bi tiriliọnu kan ati miliọnu lọna mejidinlọgọta-le-ni-ẹẹdẹgberin naira (N1.758,196,44,844Tr).
Aṣofin Yishawu sọ pe wọn ṣafikun awọn owoya kan to ye ni sisan sinu i ẹọṣ una owo naa ki Ile to fọwọ si i.
Lẹyin ti wọn sọ abadofin iṣuna owo ilu naa di ofin, Aṣofin Ọbasa dupẹ lọwọ awọn akẹgbẹ rẹ fun iṣẹ takutakun ti wọn lati ri i daju pe aṣeyori ba sisọ abadofin iṣuna owo naa di ofin.
Bakan naa ni o o ki gbogbo wọn fun ipalemọ ọdun tuntun, ki wọn si ṣọra ṣe ni asiko yii fun aabo ara wọn ati awọn eniyan wọn.
Leave a Reply