Russia Ṣe Ìkọ̀lù Dírònù, Ohun Ìjà Olóró sì orílẹ-èdè Ukraine
ni alẹ ọjọ Abameta, ti o dojukọ awọn ohun amayederun agbara ati ọkọ oju irin jakejado orilẹ-ede naa.
Awọn oṣiṣẹ Ukraine sọ pe awọn ikọlu naa pa o kere tan eniyan mẹwa, ti awọn ọmọde meji wà pẹlu wọn, ni ilu ariwa ila oorun Kharkiv.
Ile-iṣẹ Aabo Russia sọ pe “awọn ọmọ ogun rẹ ṣe awọn ikọlu ni alẹ kan si awọn ile-iṣẹ ologun-ile-iṣẹ Ukraine, awọn papa ọkọ ofurufu ologun, ati awọn ohun elo agbara.”
Olugbe kan, Hanna, ṣalaye ìṣẹ̀lẹ̀ naa pe “Nigbati a de ibi ni iṣẹju ogún lẹhin ìbugbamu naa, Mo ro pe n o yarọ ni. Emi ko le so awọn ọrọ meji pọ, awọn ẹsẹ mi si n gbọn. Awọn eniyan lasan ni wọn ngbe nibẹ. Kini wọn n wa, kíni wọn n dojukọ?”
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san