Ni ákokó aawe ati ẹ̀mí oṣù Ramadan mímọ́, Dangote Foundation ti fi Ogorun Egberun Àpò Irẹsi ṣe ìtọrẹ fún àwọn olùgbé to ku díẹ kaato fun ní gbogbo Ìpínlẹ̀ Kano ní Àríwá Ìwọ̀ Oòrùn Nàìjíríà.

Akọ̀wé fún Ìjọ́ba Ìpínlẹ̀, Alhaji Umar Farouk Ibrahim, ló ṣe àfihàn ìpínkiri náà, ẹni tó ṣáájú àwọn aṣojú láti bẹ̀rẹ̀ sí í pín àwọn ìtọrẹ náà sí àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìnlélógójì ní ìpínlẹ̀ náà.
Ẹgbẹ́ náà tún ṣe ìpínkiri òpópónà sí òpópónà káàkiri àwọn òpópónà pàtàkì ní ìlú Kano, tí wọ́n fojú sí àwọn aláìní, àwọn aláìlera àti àwọn ẹgbẹ́ aláìlera mìíràn.

Ó ṣàlàyé pé, ìgbìmọ̀ náà ti ṣe àṣeyọrí láti fi àwọn ìtọrẹ náà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìnlélógójì, wọ́n sì tún ń ṣàfihàn àwọn ibi tí ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìlera wà fún ìpínkiri òpópónà tààrà.
Àwọn olùgbàlejò kan tí wọ́n gba ninu ìrẹsi náà fi ọpẹ́ hàn fún ìrànlọ́wọ́ náà, wọ́n sì ṣàpèjúwe eto náà pé àkókò àwẹ̀ to bọ́ sì rẹ́gí lo ṣe.
Pínpín ìtọrẹ ti Ramadan náà tún de ọdọ àwọn ẹlẹ́sìn miran pẹ̀lú ati ọdọ àwọn aláìní olùgbé lo jàǹfààní ètò náà jákèjádò òpópónà Kano.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san