Browsing Category
ÌRÒYÌN YÀJÓ-YÀJÓ
This is a category for TRENDING NOW
Igbákejì ààrẹ Shettima bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́
Igbákejì ààrẹ Nàìjíríà tuntun , Kashim Shettima bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun,tí ó sì ń fi dá àwọn ọmọ Nàìjíríà lójú pé Bọla Tinubu yóò pèsè ìṣèjọba tó dára ní orílẹ̀-èdè.
Wọ́n búra fún Shettima…
Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, Jonathan ṣàpèjúwe olóògbé Dokpesi gẹ́gẹ́ bí olùṣòwò…
Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, Goodluck Jonathan, ti banújẹ́ lórí ikú olùdásílẹ̀ DAAR Communications, Olóyè àgbà Raymond Dokpesi.
Nínú ìfiránṣẹ́ ìkẹ́dùn kan, Jonathan sọ pé Nàìjíríà ti pàdánù olólùfẹ́…
Tíṣẹ́ kò bá pẹ́ni, ẹnìkan kìí pẹ́ṣẹ́
Ààrẹ Bola Tinubu, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lónìí gẹ́gẹ́ bí adarí Nàìjíríà.
Ó wọṣẹ́ ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ní déédé agogo kan ààbọ̀ kọjá ìṣéjú kan.
Eléyìí tẹ̀lé ìbúra fún un gẹ́gẹ́ bíí ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà…
Ààrẹ Tinubu ṣèdárò olóògbé Dokpesi
Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu GCFR, ṣèdárò ikú olùdásílẹ̀ Daar Communications, tí ó ni African Independence Television (AIT) àti Raypower, Olóyè Raymond Dokpesi.
Dokpesi jẹ́pè olúwa ní ọjọ́ Ajé, ní ilé-ị̀wòsàn kan ní…
Ìbúra: Ìjọba UK kí Ààrẹ Tinubu àti igbákejì rẹ̀ Shettima kú oríire
Ìjọba UK kí Ààrẹ Tinubu àti igbákejì rẹ̀ Shettima kú oríire níbi ayẹyẹ ìbúra fún wọn gẹ́gẹ́ bí́ ààrẹ àti igbákejì orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní sísẹ̀ntẹ̀lé.
Eléyìí wà nínú àlàyé kan tí Aṣojú British sí…
NNPC Ṣàtẹ́wọ́gbà yíyọ Àdínkù owó orí epo
Ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó ètò epo ilẹ̀ lórílẹ̀-èdè, ti sọ pé òun Ṣàtẹ́wọ́gbà ìpinnu ìjọba àpapọ̀ láti yọ Àdínkù owó orí epo mọ́tó.
Nígbá tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, ọ̀gá àgbà aláṣẹ NNPC , Mallam…
Anthony Dokpesi Di Olóògbé
Pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn ni a ṣe tufọ ikú Olóyè Agba Raymond Aleogho Anthony Dokpesi (Ezomo of Weppa-Wanno Kingdom) tó dágbére fáyé ní ọjọ́ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, Ọdún 2023. Baba rere ni, Ọkọ gidi ni fún aya rẹ̀
Ẹni ti araye fẹran ni…
Ìgbòkègbodò Ọkọ̀: Makinde Pàṣẹ Kí Ìgbìmò Tó Ń Darí Ibùdókọ̀ Ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Di Títúká.
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti kéde láti tú Ìgbìmọ̀ to n darí Ibùdókọ̀, labẹ Alága rẹ, Alhaji Mukaila Lamidi, ti wọn tún mọ sí 'Auxiliary' ká.
Ẹni tíì ṣe Adarí Òṣìṣẹ́ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Segun Ogunwuyi ló fí ìdí ọrọ yi múlẹ̀ nínú atẹjade kan.…
Makinde Yan Adarí Òṣìṣẹ́ Àti Akọwe Ìròyìn Míràn Fún Sáà Kejì Ìṣèjọba Rẹ
Lẹ́yìn bíi wákàtí diẹ tí ètò Ìbúra wáyé tí Makinde bẹrẹ ìṣèjọba gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún sáà ẹlẹẹkeji ni o ti yan ẹni tíì ṣe ọkan lára àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹlẹ rí, Segun Ogunwuyi gẹ́gẹ́ bíi Adarí Oṣiṣẹ.…
Ọ̀RỌ̀ ÀÀRẸ BOLA TINUBU: ÀYÍPADÀ TUNTUN TI DÉ BÁ ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÍJÍRÍÀ
Ẹ̀yin ènìyàn mi lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà,
Mo dúró sí wájú yin lónìí, Ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, Ọṣụ̀ Karùn-ún, Ọdún 2023 láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí ẹ fi rán mi. Ìfẹ́ tí mọ ní sí orílẹ̀-èdè yìí dúró digbí. Ìgbàgbọ́ mìi nínú yín ṣi…