Take a fresh look at your lifestyle.

Kòsí Ẹni Tó Lè Kú Láì Jẹ Pé Ọlọrun Fọwọ́ Síi: Ọ̀tún Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn

Ọ̀tún Olúbàdàn ilẹ Ìbàdàn, Aṣòfin Adewolu Ladoja ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé kosi enikan to lè kú láì ní ọwọ́ Ọlọrun nínú, nígbà tó sọ pé Ọba Balógun,Allí Okunmade II gbé ìgbé ayé rere fún ìgbà díẹ tó lo gẹ́gẹ́ bíi Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn. Ọ̀tún…

Makinde Fọwọ́ Sí Gbígbé Ọ̀pá Àṣẹ Àti Adé Fún Ọba Méjì Ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti fọwọ́ sí gbígbé ọ̀pá àṣẹ àti adé fún Ọ ififiti ìlú Fiditi, Ọba Sikiru Akanni Oyelese ati Elempe ti Tápà, Ọba Titilola Oyekanmi Sunday. Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde ti Kọmísánnà fún Ìjọba Ìbílẹ̀ àti Òye Jíjẹ,…

Ìwà ìjinigbé: Ilé Aṣòfin Èkó rọ Gómìnà Sanwo-Olu láti gba àwọn ẹ̀ṣọ́ abẹ́lé ‘Neighbood…

Pẹ̀lú bí ìwà ìjinigbé ṣe ń pọ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ilé Aṣòfin Èkó ti rọ Gómìnà Sanwo-Olu láti gba àwọn ẹ̀ṣọ́ abẹ́lé 'Neighbood Watch' síi láti lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò yòókù. Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà…

Ayẹyẹ Ọdún Kejì Lórí Ìtẹ́: Olúbàdàn Pé Fún Àdúrà Àti Ìfẹ́ Lásìkò Ramadan

Olúbàdàn Ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Lekan Balogun Allí Okunmade II dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun fún oore ọ̀fẹ́ àti anfààní tó fi fún ùn lati rí odun keji lórí ìtẹ́ àwọn baba rẹ̀. Bákan náà, Oba Balógun tun dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn igbimọ rẹ fún ìrànlọ́wọ́ àti…

Akọ̀wé àgbà Ilé Aṣòfin Èkó kìlọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ̀ láti má ṣe fi àwọn ìròyìn àṣírí nípa iṣẹ́ jáde

Akọ̀wé àgbà Ilé Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó, Amòfin Ọlálékan Ọ̀náfẹ̀kọ̀ ti ṣe kìlọ̀ kìlọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ̀ Ilé Aṣòfin náà àti ti Ìgbìmọ̀ Aṣàkóso Ilé Aṣòfin náà láti má ṣe fi àwọn ìròyìn ẹlẹ́nu iṣẹ́ nípa Ilé Aṣòfin náà síta láìgba àṣẹ. Ọ̀nàfẹ̀kọ̀…

Oyè Jíjẹ Ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́: Makinde Ṣèlérí Láti Mú Àtúnṣe Débá Ìgbìmọ̀ Lọ́ba Lọ́ba

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ṣèlérí pé ìṣèjọba òun ti ṣetán láti mú àtúnṣe dé bá ìgbìmọ̀ àwọn l'ọba l'ọba àti oyè jijẹ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nígbà tó fi kún pé àsìkò ti tó fún èyí. Makinde ló sọ ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ṣe ìpàdé pẹ̀lú…

Makinde Fi Ẹ̀bùn Ọkọ̀ Méjìdínlọ́gbọ̀n (28) Fún Àwon Ọmọ Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ṣèlérí wí pé, bo tilẹ̀ jẹ́ pé ohun gbogbo gbé owó lórí, ìṣèjọba òun yóò tẹ̀ síwájú láti máa ṣe ohun tí yóò mú kí ará tu àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Gómìnà lo sọ ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó n fi ọkọ̀ elérò…
button