Igbakeji aarẹ orilẹ ede Naijiria, ojọgbọn Yemi Osinbajo ti ni awọn ipenija ti orilẹ ede Naijria ń dojukọ ko ni pe di ohun igbagbe laipé.
Osinbajo,sọrọ yii lọjọBọ lasiko to n tẹwọgba awọn ẹgbẹ alatilẹyin fun aarẹ Muhammadu Buhari , iyẹn ,Muhammadu Buhari Osinbajo (MBO) Dynamic Support Group nile aarẹ to wa niluu Abuja.
igbakeji aare tun tẹsiwaju pe “Gbogbo awọn ipenija to n dojukọ orile ede Naijria bayii, ni ko ni pẹ di ohun igbagbe , ti orilẹ ede Naijria yoo tun pada di orile ede amuyangan.
“A o ko gbọdọ rẹyin lati ri i pe orilẹ ede Naijria jẹ ọ̀kan , ki a si ni ipinnu ti yoo lee mu orilẹ ede Naijria tun goke agba.”
Leave a Reply