Ààrẹ Muhammadu Buhari ti bá ẹbí , ijọba ipinlẹ Cross River, ile igbimọ asofin agba ati ọ̀rẹ́ adari ile igbimọ asofin tẹlẹri oloogbe Joseph Wayas dárò .
Asofin Joseph Wayas jẹ ọmọ ọgọrin ọdun nigba ti o dagbere fáyé pe o digbose .
Aarẹ Buhari tẹsiwaju pe orilẹ ede Naijiria mọrírih ipa pataki ti oloogbe naa ko lasiko ti o jẹ adari ile igbimọ asofin agba lorilẹ ede Naijria. Ọmọ ọdun mejidinlogoji ni oloogbe Joseph Wayas lasiko ti o jẹ adari ile igbimọ asofin agba lorilẹ ede yii.
Aarẹ Buhari wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ́ oloogbe naa si afẹ́fẹ́ ire.
Leave a Reply