À̀àrẹ Bùhárí kí Gómìnà Ikpeazu kú ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀

Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ti bá gómìnà Okezie Ikpeazu ti ìpínlẹ̀ Abia yọ̀ lórí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀,tí ó jẹ́ ọjọ́ kejì-dín-lógún oṣù kẹwàá, ọdún 2021.Gómìnà ọ̀hún pé ọmọ ọdún mẹ́tà-dín-lọ́gọ́ta.

Aarẹ darapọ mọ gbogbo idile Ikpeazu, awọn ọrẹ ati alabaṣiṣẹpọ rẹ ni gbigbadura fun ilera  ati ẹmi gigun fun Gomina naa.

Aarẹ Buhari gbadura fun Gomina Ikpeazu fun  alekun oore ninu ọdun titun to n bọ, ti aarẹ Buhari si gbagbọ pe gbogbo awọn adawọle rẹ gẹgẹ bii alakoso ilu rẹ yoo wa si imuṣẹ ni agbara ọlọrun.

Comments (0)
Add Comment