ẹ se isẹ́ yín bí isẹ́, ẹ̀yin ilé-isẹ́ a-dójú-tòfò

Aarẹ orilẹ ede Naijiria, Muhammadu Buhari  ti rọ awọn ile-isẹ a-doju-tofo lati maa se isẹ wọn bi isẹ́  lorilẹ ede Naijiria , ni eyi ti wọn yoo se lee máa mu ileri wọn sẹ fun awọn onibara wọn.

Aarẹ sọrọ yii lọjọBọ  lasiko ti ẹgbẹ akojọpọ awọn ile-isẹ a-doju-tofo n fi oye da aarẹ lọla gẹgẹ bi  baba isalẹ ẹgbẹ wọn , ni eyi to waye nile aarẹ to wa niluu Abuja.

oludari ẹgbẹ ọhun, Muftau Oyegunle naa wa gbosuba fun aarẹ Buhari fun gudu gudu meje ,yaya mẹfa ti o ti n se lati mú  ìsẹ́ ohun òsì kuro lorilẹ ede Naijiria , nipa ọkan-o-jọkan awọn eto ti ijọba aarẹ Buhari gunle, lara wọn ni eto idagbasoke ironilagbara fun awọn ọdọ, ati eto ipese  owo ati ibugbe fun awọn ara ilu.

Comments (0)
Add Comment