COVID-19: Awọn eniyan ẹẹ́rinlá-din-ni-ojì-le-nigba tun ti ni aarun Corona,àwọn mẹ́fà pàdánú ẹ̀mí wọn

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun lorilẹ ede Naijiria tun ti kede pe awọn  ọmọ orilẹ ede Naijiria , ti iye wọn jẹ́ ẹẹ́rinlá-din-ni-ojì-le-nigba (226)  ti ni aarun bayii, ti awọn eniyan mẹfa si ti padanu ẹ̀mí wọn.

Ni bayii, apapọ iye awọn  eniyan to ti ni aarun Corona lorilẹ ede Naijiria  ti jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàrún-le-ni-ọ̀kẹ́ -mẹ̀wá-din -ni- ọ́rin-din-lẹwá (20,8630).Ní ilu Abuja , iyẹn FCT  wọn ni mẹ́ta-le-ni-àádọ́rin ( 73 ) nigba ti ipinlẹ jẹ Plateau mẹrinlelọgbọn (34).

Awọn ipinlẹ ti aarun naa tun ti gbẹ jẹyọ ni,  ipinlẹ Eko marundinlọgbọn  (25), Gombe mejilelogun (22), Abia , mẹrindinlogun(16), Osun, mẹtala (13), Kano, meje (7), Rivers, meje  (7), Ekiti, mẹfa  (6), Kaduna, mẹfa  (6), Oyo, mẹfa  (6), Delta, marun un (5), Edo, mẹta  (3) Jigawa, meji (2), ati  Nasarawa, ẹyọ kan (1).

 

Comments (0)
Add Comment