Ààrẹ Buhari gbóríyìn fún àjọ UNDP

Aarẹ Muhammadu  Buhari ti gboriyin fun isẹ takun-takun ti  ẹ̀ka ajọ agbaye to n mojuto eto idagbasoke  n se lorilẹ ede Naijiria papaap julọ lati pese awujọ to se e gbe fun awon to wa ni ẹkun ila oorun Ariwa orilẹ ede Naijiria.

Aarẹ sọrọ yii lọjọBọ nilee aarẹ to wa niluu Abuja,lasiko to gba asoju ẹ̀ka ajọ agbaye to n mojuto eto idagbasoke arabinrin Ahunna Eziakonwa lálejò.

Aarẹ ni ; ”Ijọba orilẹ ede Naijiria n sa gbogbo ipá rẹ lati ri i pe wọn da gbogbo awon ti ogun tabi wahala le kuro niluu wọn kuro pada si orírùn wọn. .”

Aarẹ tun wa dupẹ lọwọ arabinrin  Eziakonwa  bo se wa si ile abinibi rẹ orilẹ ede Naijiria, “ati pe ilé rẹ lo wa ,”  inu wa dun bi arabinrin  Eziakonwa, ọmọwe  Ngozi Okonjo-Iweala, ti o wa ni ajọ to n mojuto to  eto okoowo agbaye ati Amina Mohammed, ti o jẹ igbakeji  alakoso akọwe agba  fun ajọ agbaye .

Arabinrin Eziakonwa  wa sọ pe; ”ẹ̀ka ajọ agbaye to n mojuto eto idagbasoke  yoo se gucu gudu meje yaya mẹfa lati mu eto idagbasoke ba awọn ọ̀dọ́ , nipa eto ironilagbara,imọ ẹ̀rọ, eto ọrọ aje ati iyipada ojú ọjọ́.

 

Comments (0)
Add Comment