Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà -Ààbò Orílẹ̀ -èdè àti ìṣọ̀kan di ọwọ́ọ yín

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 280

Mínísítà fún Àlàyé àti Àṣà  orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà Alhaji Láí Mòhámmèd ti gba àwọn oníròyìn níyànjú láti rọra lo òmìnira tí wọ́n ní lórí iṣẹ́ wọn,kí wọ́n ó sì dúró ṣinṣin lórí ìṣọ̀kan àti ààbò orílẹ̀ -èdè wa.

Minisita ti  Ọgbẹni Oladipo okunnu, Oludari ni Ile -iṣẹ ti Alaye ati Aṣa ṣoju sọ eyi ni ọjọ iṣẹgun ni Ilu Abuja, nibi apero kan  ti  akori rẹ jẹ  Alaye jẹ adun gbogbo eniyan.

O sọ pe Ijọba n rii awọn oniroyin gẹgẹ bi awọn alabaṣiṣẹpọ lọwọlọwọ fun ajọfọwọsowọpọ lati ṣaṣeyọri lori awọn nkan ti awọn baba nla wa jẹya fun.

Minisita naa ran awọn olugbọ leti pe, awọn iroyin irọ, alaye ti ko tọ ati ọrọ ikorira le ja fa rogbodiyan ninu ilu ati pe o tun ni ipa nipa aburu lori iṣọkan orilẹ -ede wa, nitorinaa a gbọdọ yago fun iru  iṣe bayii.

O sọ pe a gbọdọ ṣe akiyesi nigbagbogbo pe, aabo  ati ipo orilẹ -ede wa ati awọn ara ilu fun idagbasoke otitọ ati igbega gbọdọ ṣe pataki pupọ. Ti o si ṣeleri pe ohun yoo tẹsiwaju lati maa ṣe atilẹyin fun awọn oniroyin lori eyi.

Nibayi, Igbimọ Alase akọwa awọn oniroyin ni Naijiria, Francis Nwosu tun rọ awọn oniroyin lati tera mọ  ojuse awujọ lakoko ti  wọn ba wa lẹnu  iṣẹ.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button