Pẹ̀lú àwọn làásìgbò àti ìgbógun ti ìwà ọ̀daràn káàkiri orílẹ̀-èdè, ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti tún tẹnumọ pé òhun kò ní fọwọ́ hẹ ìṣọ̀kan ìjọba òhun.
Minisita Alaye ati Aṣa ti orilẹ -ede, Alhaji Lai Mohammed sọ eleyi di mimọ lakoko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn oniroyin Voice of Nigeria ni ilu Abuja, ni ipari ọsẹ.
Minisita naa sọ pe, ijọba n gba gbogbo ọna lati gbogunti awọn iwa ọdaràn, ṣugbọn o tun wa rọ awọn ara ilu lati tunbọ le dahun ati gbaradi fun igbogunti laasigbo niwọnba agbara wọn nitoripe,ijọba nikan ko le daaṣe.
Awọn eniyan gbọdọ jẹ ọlọgbọn ati oloye to ni lati mọ pe aisiabọ yii jẹ nnkan ti o n kan gbogbo eniyan.
Alhaji Mohammed sọ pe ijọba ti n ṣiṣẹ pẹlu ribiribi lori ọrọ awọn ọdaràn laibikita ẹni ti wọn jẹ, ibiti wọn ti wa tabi ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ wa.
O sọ pe orukọ eyikeyi ti ko baa jẹ iṣamisi wọn, ko jẹ pataki rara.Ọdaran ni gbogbo wọn jẹ , ti a si gbọdọ wa wọn ri.
Boya alejò ni wọn tabi onile , ijọba yoo tẹsiwaju lati fi ọwọ lile mu wọn titi ti wọn yoo fi ṣẹgun wọn patapata.
Minisita naa kọ asọye ti o sọ pe ijọba n fun awọn ọdaran ni tọju ti oyatọ.
Leave a Reply