Olùdarí ikọ̀ ogun HADIN KAI, ajagun Christopher Musa, ti fi dá àwọn ọmọ Nàìjíríà lójú pé àwọn aláṣẹ ológun kò fìgbà kan túra sílẹ̀.
Ajagun Musa fidi eyi mulẹ nitori, bi ọpọlọpọ awọn onijagidijagan ṣe tuba ni Ariwa Ila -oorun ati ibẹru bojo ti eyi ti da si ọkan ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹ -ede Naijiria.
Alakoso ikọ naa ti o n sọrọ ni olu Ile -iṣẹ HADIN KAI lakoko ti o n ṣe ipade pẹlu ẹgbẹ Awọn oniroyin nibi irin -ajo kan ti o rin,o sọ pe, awọn oniroyin ti pese atilẹyin takuntakun pataki julọ lakoko yi,ti ologun si mọ riri rẹ.
Ajagun Christopher tun ṣe akiyesi pe, botilẹ jẹ pe, igbogun t’awọn ọlọtẹ ni Ariwa Ila -oorun ti gba igba pipẹ, ti o si mu agbegbe naa fa sẹhin ninu idagbasoke.Ologun ko tura silẹ rara nipa ituba lọpọ yanturu to n ṣẹlẹ.
O sọ pe ologun n ṣa gbogbo ipa rẹ nipa lilo ofin kariaye lati yanju ọrọ Boko Haram, paapaa julọ lasiko ti awọn apanilaya n tuba lọpọlọpọ.
O tọka si pe, aabo ati iṣọkan orilẹ -ede Naijiria jẹ awọn logun pupọ, fun idi eyi, ologun yoo ṣa gbogbo ipa wọn lati rii daju pe olukaluku gbadajọ ododo ti o si tun wa rọ awọn oniroyin fun ifọwọsowọpọ wọn fun awọn alaye ti ara ilu ba nilo.
Leave a Reply