Ẹ̀yin dókítà, ẹ fagilé ìyansẹ́lódì yín, kí ẹ sì padà sẹ́nu isẹ́ ní kíákíá- Adajọ Basha.A.Alkali

Ilé- ẹjọ́ tó ń gbọ́ awuye-wuye lórí ọrọ to ba jẹ mọ awọn osisẹ ati ijọba ((Nigeria Industrial court) to n gbẹjọ gbọ́nmi-si -omi-ò- to waye laarin ijọba apapọ  ati egbe  awon dokita lorile ede Naijiria(Resident Doctors) ti pàsẹ pe ki  awọn dokita ile iwosan ijọba  pada sẹnu isẹ wọn ni kiakia.Ki won si bẹrẹ isẹ wọn lẹyẹ- o-jọkà,

 

     

Adajo Basha.A.Alkali lo dajọ naa pe ki awọn dokita pada sẹnu isẹ wọn, ki  wọn si maa ijoba apapọ fori-kori lati yanju aawọ to wa laarin wọn ni itubi-inubi.

Bakan ni ki awon agbẹjọro ijọba ati agbẹjọro egbe aọon dokita lo forikori,ki wọn si mu ọjọ́ ti wọn yoo pada wa sile ẹjọ.

Amọsa,Femi Aborisade to jẹ agbẹjọro fun ẹgbẹ awọn dokita to gun le iyansẹlodi ọhun, lo ti jẹ ko di mimọ pe awọn yoo  forikori pẹlu awọn onibara wọn,iyen egbe awọn dokita boya wọn yoo tesiwaju ninu ẹjọ to wa nile ẹjọ kotẹmilorun, tabi ki wọn fopin si iyansẹlodi wọn.

 

Comments (0)
Add Comment