Ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀ FEC fọwọ́sí iye owó tótó bílíọ̀nù méjìdín-lógójì Náírà Fún Àwọn òpópónà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

Ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀ ti fọwọ́sí iye owó tótó bílíọ̀nù méjìdín-lógójì fún píparí àwọn  iṣẹ́ àkànṣe òpópónà ní ìpínlẹ̀ márùn – ún jákàjádò orílẹ̀-èdè.

Minisita fun Iṣẹ ati Ibugbe, Babatunde Fashola ṣe afihan eyi ni  Ọjọbọ, lakoko ti o n ba awọn oniroyin Ile ilu sọrọ, ni ipari ipade minisita ti ọsẹ yii ti aarẹ Muhammadu Buhari ṣe alaga.

O ṣe atọka si awọn ipinlẹ ti yoo  j’anfani naa: Anambra, Imo, Bayelsa Nasarawa ati Benue,o  ṣafikun pe gbogbo awọn iṣẹ akanṣe naa jẹ iṣẹ ti awọn ijọba iṣaaju ṣe pati.

Gẹgẹ bi Fashola ṣe sọ: “Wọn kii ṣe awọn iṣẹ akanṣe tuntun, wọn jẹ awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba wa ba nilẹ ti a si n gbiyanju lati pari. Nitorinaa a ni lati ṣatunyẹwo idiyele wọn  nitoripe iṣẹ ọlọjọ pipẹ ni, ti  awọn idiyele wọn si ti yipada.

“Nitorinaa, akọkọ ni iṣẹ  opopona 13.5-kilometer kan lati opopona Onitsha-Owerri si Okija-Ihembosi-si Ugbor si Ezinifite ni Ijọba ibilẹ Nnewi South ti Ipinle Anambra.

“Ekeji ni isọdọkan ogun kilomita  ti opopona Yenagoa si Kolo ati Otuoke ati Bayelsa Palm ni Ipinle Bayelsa.

Ẹkẹta ni opopona Nasarawa si Loko ti o jẹ kilomita mẹrinle-laadọrin . Iyẹn ni ọna ti wọn gbeṣẹẹ sita ni, ni ọdun 2006, nitorinaa o jẹ ọdun mẹẹdogun  loni, ti ko si tii pari. Opopona yii lo so Afara Loko-Oweto pọ.

 

 

 

 

 

Ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀ FEC fọwọ́sí iye owó tótó bílíọ̀nù méjìdín-lógójì Náírà Fún Àwọn òpópónà
Comments (0)
Add Comment