Igbákejì ààrẹ,Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀sínbàjò polongo ìtẹ̀sìwájú lórí Ìṣòwò iṣẹ́ àkànṣe Gáásì ní ìlú adúláwọ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

Igbákejì ààrẹ orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Ọ̀sínbàjò sọ pé àwọn akitiyan ti ó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ láti fi òpin sí ìdàgbàsókè àwọn iṣẹ́ àkànṣe gáásì ní ilẹ̀ adúláwọ̀ lòdì sí àwọn ìpilẹ̀ aìṣegbé  àti ìṣedéédé tí ó wà nínú àwọn àdéhùn àgbáyé.

O sọ eleyii di mimọ  lakoko ti o n sọrọ nibi  apejọ lori ayelujara, ti akọle rẹ jẹ: Oju -ọjọ, Rogbodiyan, ati eto bi awọn eniyan ṣe pọ si ni adulawọ,  ti ẹgbẹ to n mojuto rogbodiyan lagbaye, ẹgbẹ ọba adulawọ,ati awọn atẹjade Asiri Adulawọ lapapọ n ṣagbekalẹ rẹ  loni.

Ọjọgbọn Ọsinbajo maa n   sọrọ ni awọn apejọ lọlọkan ọjọkan lori nina owo lori akanṣe iṣẹ gaasi ni awọn orilẹ-ede to sese ndagbasoke, bii Naijiria, ti o si n  ṣagbero fun iyipada to ṣedeede ati ilowosi ti otunbọ munadoko  si ibi-afẹde ti Net-Zero Emission ni ọdun 2050.

Nibi ipade kan ti o waye ni oṣu keji  pẹlu ọmọ ile-igbimọ aṣofin ti Ilu Gẹẹsi ati Alakoso COP26, Ọgbẹni Alok Sharma, Ọjọgbọn Osinbajo tun tẹnumọ iṣatilẹyin ati ifaramọ Naijiria lori adehun Iyipada oju-ọjọ, ti o si tọka si awọn idiwọ   lori ninawo si awọn iṣẹ akanṣe gaasi ni awọn orilẹ-ede adulawọ  bi ifaseyin ti o lagbara.

 

Igbákejì ààrẹỌ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀sínbàjò polongo ìtẹ̀sìwájú lórí Ìṣòwò iṣẹ́ àkànṣe Gáásì ní ìlú adúláwọ̀
Comments (0)
Add Comment