COVID-19: Àwọn ènìyàn ọ̀kan-din-ni-okòó-le-ni-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta míràn ti ní àrùn Corona, ènìyàn méjìdínlógún ti di olóògbé

Àwọn ènìyàn ọ̀kan-din-ni-okòó-le-ni-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta  (519) míràn ti ní àrùn Corona, COVID-19 lorilẹ ede Naijiria bayii.

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹ ede Naijiria, iyẹn ,Nigeria Centre for Disease Control NCDC lo kede rẹ lọjọ  Isẹgun lori ẹrọ ayelujara  wọn. Bakan naa, ni ajọ naa tun kede pe awọn ènìyàn méjìdínlógún lo ti di olóògbé .

Awọn ipinlẹ mẹẹdogun  ni arun naa to gbe jẹyọ, awọn ipinlẹ  naa ni – “Lagos , ọgọfa (120), Ondo,àádọ́fà (110), Rivers,mẹ̀rin-le-ni-àádọ́rin (74), Edo,mẹtalelọgọrin (63), FCT, mejidinlọgọta (58), Oyo, mọkanlelọgbọn (31), Kaduna , mẹẹdogun(15), Bayelsa, mọkanla (11), Cross River, mọkanla (11), Delta, mọ́kànlá (11), Kano, márùn ún (5), Ogun, mẹ́rin (4), Plateau, mẹ́ta (3), Adamawa, méjì (2), ati Gombe, ẹyọkan (1).

Nibayii , iye aawọn to ti ni aarun COVID-19 loril ede Naijiria jẹ,ọ̀kẹ́-mẹ̀wá-le-ni-mẹ̀ta-din-ni-ọ́ta

(200,057) nigba ti awọn eniyan ẹ̀ẹ́dẹ́gbàrún-le-ni-ọ̀kẹ́-mẹ̀sán-din-ni-ọ̀kan-le-ni-ọ́rin ( 188,719)

ti gba iwosan, nigba ti awọn eniyan mẹ̀ta-din-ni-ojì-le-ni-ẹgbẹ́ẹ̀talá ( 2,637) si ti oloogbe.

18 DeathsCOVID-19: Nigeria Confirms 519 New Cases
Comments (0)
Add Comment