Ààrẹ Bùhárí ń darí àpèjọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀

Etitayọ Fauziat Oyetunji

Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ń darí àpèjọ ìgbìmò aláṣẹ àpapọ̀ lórí ayélujára ní yàrá àpèjọ arábìnrin àkọ́kọ́,ní olú ìlú, Àbújá.

Ọjọgbọn Yẹmi Ọsinbajo ati akọwe fun ijọba apapọ, Boss Mustapha wa nijoko nibi apejọ naa,eyi ti o bẹrẹ ni agogo mẹsan an owurọ.

Awọn ti o tun wa nibi apejọ naa ni,  minisita fun eto ibaraẹnisọrọ ati Asa, Lai Mohammed; Agbẹjọro Agba ati Minisita fun Idajọ, Abubakar Malami; ati ọrọ orisun Omi, Suleiman Adamu.

Awọn yooku ni  minisita fun Isuna, inawọ ati Eto Orilẹ -ede, Zainab Ahmed;  iṣẹ ati ibugbe, Babatunde Fashọla ati eto ọrọ Inu ilu, Rauf Aregbeshola.

Ọga agba fun awọn oṣiṣẹ  ijọba apapọ, Folashade Yemi-Esan ati awọn minisita miiran n kopa ninu apejọ ọhun lati awọn ọfiisi wọn lọlọkan ọ jọkan ni ilu Abuja.

Iṣebura fun awọn kọmiṣọna igbimọ idibo olominira orilẹ-ede(INEC ) meta ni o kọkọ waye ṣiwaju ipade naa.

Awọn ti wọn ṣe  ibura fun ni Dokita Baba Bila ti o ṣoju fun agbegbe ariwa ila-oorun, Ọjọgbọn Sani Adam, aringbungbun ariwa ati Ọjọgbọn Abdullahi Abdu, ti o ṣoju fun ariwa iwọ oorun.

Alaye lẹkunrẹrẹ nigba miran an…

 

 

 

 

Ààrẹ Bùhárí ń darí àpèjọ ìgbìmò aláṣẹ àpapọ̀
Comments (0)
Add Comment