Ọba ilẹ̀ Adúláwọ̀ agbábọ́ọ̀lù ẹlẹ́yin orí tabili “ITTF Africa Cup”, Omar Assar àti Hana Goda ti ṣetan láti ṣaaju àwọn akópa nibi idije”Singapore Smash” ti yóò bẹrẹ láti ọjọ kọkàndínlógún oṣù keji titi di ọjó kinni oṣù kẹta, ọdún 2026 ní orílẹ-èdè Singapore.
Ògbóntàrigi, Assar wọ ipele eleni merindinlogun ní Singapore ní odún méjì seyin, ní láti mura daradara se jù béè lọ ní ọdún yi.
Quadri Aruna to ṣe dáradára julọ ní ilè Adúláwọ̀ nínú ìdíje nígbà kan ri náà yóò dara pọ̀ mọ́ wọn.

Ikọ̀ Nàìjíríà dé ìpele kẹta tó kángun sí àsekágbá ní ọdún 2023, ti wọn na ògbóntàrigi to wà ni ipò Kẹrin ní àgbáyé, Tomokazu Harimoto ní ayò mẹta sì odo (3-0) kí wọn tó wá subú sọ́wọ́ Hugo Calderano. Ògbóntàrigi ọmọ ilẹ Egipti, Youssef Abdel Aziz. náà yóò dara pọ̀ mọ́ wọn.
Ogbontarigi agbalábọ̀ọ̀lu ilẹ̀ Adúláwọ̀ to kú ni, Wassim Essid, Mohammed El‑Beali, Abdel‑Kader Salifou, àti Ylane Batix,
Ni ti awọn obinrin láti ri, Dina Meshref, Mariam Alhodaby, àti Yosra Helmy ti awọn métẹ̀ẹ̀ta wá láti ilẹ̀ Égípìtì.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san