Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra Ọmowé Chukwuma Soludo ati àwọn ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ ti wọn ní pe Ohanaeze Ndigbo, ti fi ẹdun ọkan hàn lórí ipakoda Alága tẹlẹ rí fún ètò ìdìbò ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọ̀mọ̀wé Humphrey Nwosu.
Wọn ní ẹni ọwọn ní olóògbé jẹ́ tí o sí ṣe iṣé rẹ dẹ ojú àmí, láàrin ọdún 1993 lásìkò ìdìbò igba náà. Ọ̀mọ̀wé Humphrey Nwosu jade laye ni eni ọdún Metalelaadorin.
Ìròyìn sọ wí pé àwọn ẹbí olóògbé ko ti fi irọyin kankan sí afẹfẹ láti sàlàyé bí ikú ṣe wáyé, ṣùgbọ́n olóògbé jáde laye ni ọjọ́ keji oṣù mẹwàá ọdún 2024 ni ilé ìwòsan Virginia ti o wa ní Orílẹ̀-èdè U.S
Gómìnà ni ikú náà jẹ ohun o dun òun púpọ̀, o se àpèjúwe olóògbé gẹgẹ bí ènìyàn pàtàkì tó sì ni ìbẹ̀rù Ọlọrun lọ́kàn lásìkò iṣẹ rẹ.
Nínú ìwé tí Akọ̀wé fún Gómìnà ko jáde èyí ti Gómìnà Buwọ́lù, Gómìnà dáàbá pàtàkì wí pé kí wọn sọ ilẹ iṣẹ ìjọba kan ni orúkọ olóògbé náà.
Olóògbé Nwosu ni o ṣe àkóso ètò ìdìbò ọjọ́ Kejìlá Oṣù keje ọdún 1993 nígbà ìdìbò Ààrẹ Ibrahim babangida.
Nwosu ṣiṣe fún àjọ Elétò Ìdìbò Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti Ọdún 1989 sí 1993.