Take a fresh look at your lifestyle.

Òṣùwọ̀n Ìtajà Tí Nàìjíríà Ti Dínkù Sí Ìdá 15.15 Nínú Ọgọrùn – NBS

315

Ẹgbẹ́ Àjọ Àgbékalẹ̀ Ìṣirò ti Orílẹ̀-èdè (NBS) sọ pé ìwọ̀n ìtajà tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dúró sí ìdá mẹ́ẹ̀dógún àti díẹ̀ nínú ìdá ọgọ́rùn (15.15%) ní oṣù Kejìlá ọdún 2025, èyí tí ó fi hàn pé ìwọ̀nba ìdínkù owó náà jẹ́ èyí tó pọ̀jù owó oúnjẹ.

‎ Ẹgbẹ́ Àjọ Àgbékalẹ̀ Nàìjíríà náà sọ èyí di mímọ̀ nípasẹ̀ opo X rẹ̀ @NBS_Nigeria, èyí tó fi ìròyìn CPI ti oṣù Kejìlá ọdún 2025 hàn.

‎ Ọ̀gá Àgbà ti Àjọ Àgbékalẹ̀ Ìṣirò ti Orílẹ̀-èdè, Prince Adeyemi Adeniran, ló gbé ìròyìn CPI náà jáde.

‎ Àtọ́ka Iye Owó Oníbàárà (Consumer Price Index CPI) ga sí 131.2 ní oṣù Kejìlá, èyí tó ga sí pẹ̀lú 0.7 tí oṣù Kọkànlá, lẹ́yìn àtúntò CPI tí ọdún 2023 fún ìpìlẹ̀ ọdún 2024 láìpẹ́ yìí gẹ́gẹ́ bí àkókò ìtọ́kasí ìwọ̀n.

‎Lórí oṣù kan sí ìkejì, ìwọn ìtajà náà dínkù sí ìdá 0.54 nínú ọgọrùn, ó dínkù gidigidi láti ìdá 1.22 nínú ọgọrùn tí a kọ sílẹ̀ ní oṣù Kọkànlá.

‎Ìfàsẹ́yìn oúnjẹ dínkù sí ìdá 10.84 nínú ọgọrùn ọlọ́dọọdún, nígbàtí owó ọjà dínkù sí ìdá 0.36 nínú ọgọrùn olóṣooṣù, pẹ̀lú àfiwé ìdá 1.13 nínú ọgọrùn ní oṣù kọkànlá.

Comments are closed.

button