Ìjoba Orílẹ-èdè Nàìjíríà ti yan àwọn mẹ́rìnlelógún láti wakọ agbára fún ètò ìlera, ìgbìmọ̀ èyí to da lórí bi iná mọ̀nàmọ́ná yóò ṣẹ wa ni àwọn ilẹ iwosan ìjoba kakakiri.
Ìgbìmọ̀ yìí yóò rì dani wí pè ki o to di ọdún 2027 àwọn ilẹ iwosan ti ìjoba yóò ni ina mọ̀nàmọ́ná tó dángájíá.
Nìgbà ti o n sọ̀rọ̀ níbi ìfilọ́lẹ̀ ni ìlu Abuja, Mínísítà fún ètò ìlera àti ìtọjú ara ìlú , Dókítà Iziaq Salako sàlàyé wí pè ìgbìmọ̀ náà duro fún ìlérí Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíría Bola Tinubu láti ri wí pè ètò ìlera dàgbà sókè.
Dókítà Salako ni ìgbìmọ̀ yìí ti bèrè láti oṣù mẹta ọdun 2025 pẹ̀lú àwọn ti ọ̀rọ̀ kan, ati àwọn ilẹ isẹ alaadani.
Mínísítà ni èyí yóó mu ìdàgbàsókè ati atunṣe ba ètò ìlera ni Orílè-èdè Nàìjíríà.